Ẹ̀KỌ́ 03
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Gbára Lé Bíbélì?
Bíbélì sọ ọ̀pọ̀ ohun rere tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la, ó sì tún fúnni ní ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn rere. Ó ṣeé ṣe kó o fẹ́ mọ ohun tí Bíbélì kọ́ni, àmọ́ o tún lè máa ṣiyè méjì pé ṣóòótọ́ lohun ti Bíbélì sọ ṣá? Ṣó yẹ kó o gbára lé àwọn ìlérí àti ìmọ̀ràn tó wà nínú ìwé àtijọ́ yìí? Ṣé àwọn ìmọ̀ràn inú Bíbélì wúlò lásìkò tá a wà yìí, ṣé a sì lè gba àwọn ohun tó sọ gbọ́, pé a máa gbádùn ayé nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú? Àìmọye èèyàn ló gbà á gbọ́. A rọ̀ ẹ́ pé kó o ṣèwádìí bóyá ìwọ náà á gbà á gbọ́.
1. Ṣé òótọ́ lohun tó wà nínú Bíbélì àbí ìtàn àròsọ lásán ni?
“Àwọn ọ̀rọ̀ tó péye tó sì jẹ́ òtítọ́” ló wà nínú Bíbélì. (Oníwàásù 12:10) Ìtàn àwọn èèyàn ẹlẹ́ran ara bíi ti wa ló wà nínú ẹ̀, àwọn nǹkan tó sọ nípa wọn sì ṣẹlẹ̀ lóòótọ́. (Ka Lúùkù 1:3; 3:1, 2.) Àwọn òpìtàn àtàwọn awalẹ̀pìtàn jẹ́rìí sí i pé àwọn déètì, àwọn èèyàn, orúkọ àwọn ìlú àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì péye, ó sì jóòótọ́.
2. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ṣì wúlò lóde òní?
Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Bíbélì sọ tó jẹ́ pé àwọn èèyàn ò tíì mọ̀ rárá lásìkò tí wọ́n ń kọ ọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì. Ọ̀pọ̀ nǹkan tó sọ làwọn èèyàn ò fara mọ́ nígbà tí wọ́n kọ ọ́. Ṣùgbọ́n ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní jẹ́rìí sí i pé òótọ́ làwọn nǹkan tí Bíbélì sọ. Ọ̀rọ̀ inú Bíbélì “ṣeé gbára lé ní gbogbo ìgbà, ní báyìí àti títí láé.”—Sáàmù 111:8.
3. Kí nìdí tó fi yẹ ká gbà pé òótọ́ ni ohun tí Bíbélì sọ nípa ọjọ́ ọ̀la?
Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ “àwọn ohun tí kò tíì ṣẹlẹ̀.” (Àìsáyà 46:10) Ó sọ ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó péye nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan ní ọ̀pọ̀ ọdún kí wọ́n tó ṣẹlẹ̀. Ó tún sọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lákòókò tá a wà yìí. Nínú ẹ̀kọ́ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ lọ́nà tó péye, ó sì yani lẹ́nu gan-an ni!
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Wo bí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní ṣe bá ohun tí Bíbélì sọ mu, kó o sì tún ṣèwádìí nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì tó wà nínú Bíbélì.
4. Ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì bá Bíbélì mu
Nígbà àtijọ́, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn èèyàn ló gbà pé ohun kan wà tó gbé ayé dúró. Wo FÍDÍÒ yìí.
Wo ohun tí ìwé Jóòbù sọ ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ (3,500) ọdún sẹ́yìn. Ka Jóòbù 26:7, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
-
Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ náà “ayé rọ̀ sórí òfo” fi yani lẹ́nu?
Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méjì (200) ọdún sẹ́yìn ni ọ̀rọ̀ nípa bí omi ṣe ń yí po nínú ayé ṣẹ̀ṣẹ̀ yé àwọn èèyàn. Àmọ́, kíyè sí ohun tí Bíbélì sọ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ (3,500) ọdún sẹ́yìn. Ka Jóòbù 36:27, 28, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
-
Kí ló wú ẹ lórí nípa ọ̀nà tó rọrùn tí Bíbélì gbà ṣàlàyé bí omi ṣe ń yí po nínú ayé?
-
Ṣé àwọn ẹsẹ Bíbélì tó o kà yìí jẹ́ kó o túbọ̀ gbà pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ inú Bíbélì?
5. Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì
Ka Àìsáyà 44:27–45:2, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
-
Kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé wo ni Bíbélì ṣe ní ọgọ́rùn-ún méjì (200) ọdún kí wọ́n tó ṣẹ́gun ìlú Bábílónì?
* Wọ́n darí omi tó ń dáàbò bo ìlú náà gba ibòmíì. Lẹ́yìn náà, wọ́n gba ẹnubodè táwọn ará ìlú náà ti ṣí sílẹ̀ gbayawu wọlé, bí wọ́n ṣe ṣẹ́gun ìlú náà láì jagun nìyẹn. Ó ti lé ní ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ (2,500) ọdún báyìí tí Bábílónì ti pa run ráúráú. Wo ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa èyí.
Ìtàn jẹ́ ká mọ̀ pé Ọba Kírúsì ti ilẹ̀ Páṣíà àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ ṣẹ́gun ìlú Bábílónì lọ́dún 539 Ṣ.S.K.Ka Àìsáyà 13:19, 20, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
-
Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ṣẹ?
6. Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lóde òní
Bíbélì pe àkókò tá a wà yìí ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Tímótì 3:1) Wo àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tá a wà yìí.
Ka Mátíù 24:6, 7, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
-
Àwọn nǹkan tó gbàfiyèsí wo ni Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn?
Ka 2 Tímótì 3:1-5, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
-
Àwọn ìwà wo ni Bíbélì sọ pé àwọn èèyàn á máa hù ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn?
-
Èwo lára àwọn ìwà yìí lo ti rí táwọn èèyàn ń hù?
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Ìtàn àròsọ lásán ló wà nínú Bíbélì.”
-
Lérò tìẹ, ẹ̀rí tó lágbára jù lọ wo ló fi hàn pé Bíbélì ṣeé gbára lé?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì bá ohun tí Bíbélì sọ mu, àwọn ìtàn àti àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì péye, wọ́n sì jóòótọ́. Èyí fi hàn pé Bíbélì ṣeé gbára lé.
Kí lo rí kọ́?
-
Ṣé òótọ́ ni ohun tó wà nínú Bíbélì àbí ìtàn àròsọ lásán ni?
-
Àwọn apá wo nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ló bá ohun tí Bíbélì sọ mu?
-
Lérò tìẹ, ṣé ohun tí Bíbélì sọ nípa ọjọ́ ọ̀la máa ṣẹ àbí kò ní ṣẹ? Kí nìdí tó o fi dáhùn bẹ́ẹ̀?
ṢÈWÁDÌÍ
Ṣé àwọn ohun kan wà tí Bíbélì sọ nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tí kì í ṣòótọ́?
“Ṣé Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Bá Ohun Tí Bíbélì Sọ Mu?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)
Kí làwọn nǹkan tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn”?
“Mẹ́fà Nínú Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Tó Ń Ṣẹ Lójú Wa” (Ilé Ìṣọ́, May 1, 2011)
Wo bí ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Gíríìsì ṣe ṣẹ.
Wo bí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe jẹ́ kí ọkùnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí í fi ojú tó dáa wo Bíbélì.
^ Ṣ.S.K. túmọ̀ sí “Ṣáájú Sànmánì Kristẹni.” S.K. sì túmọ̀ sí “Sànmánì Kristẹni.”