Ṣé èèyàn lè wà láàyè títí láé?
Kí ni ìdáhùn rẹ?
Bẹ́ẹ̀ ni.
Bẹ́ẹ̀ kọ́.
Kò dá mi lójú.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
“Àwọn olódodo ni yóò jogún ayé, wọn yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.”—SÁÀMÙ 37:29.
ÀǸFÀÀNÍ WO LÓ MÁA ṢE Ẹ́?
Inú ẹ á máa dùn, wàá sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ.—JEREMÁYÀ 29:11.
Kì í ṣe àkókò díẹ̀ ni wàá fi gbádùn ayé ẹ, àmọ́ ńṣe ni wàá máa gbádùn ayé ẹ títí láé.—SÁÀMÙ 22:26.
ṢÉ O LÈ GBA OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ GBỌ́?
Bẹ́ẹ̀ ni! Tó o bá fẹ́ mọ ìdí tó fi yẹ kó o gba ohun tí Bíbélì sọ gbọ́, jọ̀ọ́ wo àwọn ẹ̀rí tó wà nínú ẹ̀kọ́ mẹ́ta tó wà nínú ìwé yìí. Àkòrí wọn ni: