APÁ KẸFÀ
Bí Ọmọ Ṣe Ń Yí Nǹkan Pa Dà Láàárín Tọkọtaya
“Àwọn ọmọ jẹ́ ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.”
Ọmọ bíbí máa ń múnú tọkọtaya dùn gan-an, ó sì tún máa ń gbé ọ̀pọ̀ iṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́. Tí ẹ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ, ó lè yà yín lẹ́nu láti mọ̀ pé ìtọ́jú ọmọ tuntun ló máa ń gba èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò àti okun yín. Ìyípadà nínú bí ọ̀rọ̀ ṣe ń rí lára yín àti àìsùn lè dá ìṣòro sílẹ̀ láàárín yín. Àfi kí ẹ̀yin méjèèjì ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ, kí ẹ lè bójú tó ọmọ yín, kí ẹ sì lè túbọ̀ ṣera yín lọ́kan. Báwo ni ìmọ̀ràn Bíbélì ṣe lè ràn yín lọ́wọ́, kí ẹ lè wá nǹkan ṣe sí àwọn ìṣòro yìí?
1 Ẹ FÒYE MỌ ÌYÍPADÀ TÍ ỌMỌ MÚ WÁ
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere.” Ó tún sọ pé, ìfẹ́ “kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan, a kì í tán an ní sùúrù.” (1 Kọ́ríńtì 13:
“Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní bíbá wọn gbé . . . ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀.” (1 Pétérù 3:7) Máa fi sọ́kàn pé àbójútó ọmọ ló máa gba èyí tó pọ̀ jù nínú okun ìyàwó rẹ. Ojúṣe tuntun ló délẹ̀ yìí, ó sì lè fa másùnmáwo àti ìdààmú ọkàn tàbí kó tiẹ̀ tán an lókun pàápàá. Kódà nígbà míì, ó lè kanra mọ́ ẹ, àmọ́ sùúrù ni kó o ṣe, torí pé “ẹni tí ó lọ́ra láti bínú sàn ju alágbára ńlá.” (Òwe 16:32) Máa fòye mọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀, kí o sì máa ràn án lọ́wọ́ bó ṣe yẹ.
OHUN TÍ O LÈ ṢE:
-
Ẹ̀yin Bàbá: Ẹ máa ran ìyàwó yín lọ́wọ́ láti tọ́jú ọmọ, ì báà jẹ́ láàárín òru pàápàá. Ẹ dín àkókò tí ẹ̀ ń lò nídìí àwọn nǹkan míì kù, kí ẹ lè túbọ̀ ráyè gbọ́ ti ìyàwó àti ọmọ yín
-
Ẹ̀yin Ìyá: Tí ọkọ yín bá fẹ́ ràn yín lọ́wọ́ láti tọ́jú ọmọ, ẹ jẹ́ kó ṣe bẹ́ẹ̀. Tí kò bá mọ̀ ọ́n ṣe dáadáa, ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ sí i, ṣe ni kí ẹ fi sùúrù ṣàlàyé bó ṣe máa ṣe é fún un
2 Ẹ TÚBỌ̀ ṢERA YÍN LỌ́KAN
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Wọn yóò sì di ara kan.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:
Ẹ̀yin aya, ẹ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọkọ yín pé wọ́n ń ràn yín lọ́wọ́, wọ́n sì ń tì yín lẹ́yìn. Ọ̀rọ̀ ìmoore tí ẹ bá ń sọ lè dà bí “ìmúniláradá.” (Òwe 12:18) Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa sọ fún àwọn aya yín bí ẹ ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn àti bí ẹ ṣe mọyì wọn tó. Ẹ máa yìn wọ́n torí pé wọ́n ń tọ́jú ìdílé yín.
“Kí olúkúlùkù má ṣe máa wá àǹfààní ti ara rẹ̀, bí kò ṣe ti ẹnì kejì.” (1 Kọ́ríńtì 10:24) Ohun tó bá dára jù ni kí o máa ṣe fún ọkọ tàbí aya rẹ. Ó yẹ kí ẹ̀yin tọkọtaya máa wá àyè láti jọ sọ̀rọ̀, kí ẹ máa gbóríyìn fún ara yín, kí ẹ sì máa tẹ́tí gbọ́rọ̀ ara yín. Má ṣe máa ro tara rẹ nìkan tó bá dọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀. Máa ronú nípa ohun tí ẹnì kejì rẹ fẹ́ pẹ̀lú. Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣe máa fi du ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, àyàfi nípasẹ̀ àjọgbà.” (1 Kọ́ríńtì 7:
OHUN TÍ O LÈ ṢE:
-
Ẹ má ṣe gbàgbé láti máa wá àyè tí ẹ̀yin méjèèjì nìkan á fi jọ máa wà pa pọ̀
-
Máa ṣe àwọn ohun kéékèèké tó máa mú kí ẹnì kejì rẹ mọ̀ pé o fẹ́ràn òun. O lè kọ̀wé ṣókí sí i tàbí kí o ra ẹ̀bùn kékeré fún un
3 BÍ Ẹ ṢE MÁA TỌ́ ỌMỌ YÍN
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Láti ìgbà ọmọdé jòjòló ni ìwọ ti mọ ìwé mímọ́, èyí tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà.” (2 Tímótì 3:
Ọmọ yín kò fìgbà kan kéré jù láti gbọ́ ohun tí ẹ bá ń sọ nípa Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ kó máa tẹ́tí sí yín tí ẹ bá ń gbàdúrà sí Jèhófà. (Diutarónómì 11:19) Kódà bí ẹ bá jọ ń ṣeré, ẹ máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run dá. (Sáàmù 78:
OHUN TÍ O LÈ ṢE:
-
Bẹ Jèhófà pé kó fún ọ ní ọgbọ́n tí wàá lè fi tọ́ ọmọ rẹ
-
Máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe kókó àti àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì lásọtúnsọ fún ọmọ rẹ, kó lè tètè bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ láti kékeré