Ẹ̀KỌ́ 12
Báwo La Ṣe Ṣètò Iṣẹ́ Ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run?
Ṣáájú kí Jésù tó kú, ó sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé.” (Mátíù 24:14) Àmọ́, báwo la ṣe máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù tó máa kárí ayé yìí? Bí a ṣe máa ṣe é ni pé, a máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ nígbà tó wà láyé.—Lúùkù 8:1.
À ń wá àwọn èèyàn lọ sílé wọn ká lè bá wọn sọ̀rọ̀. Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa wàásù ìhìn rere láti ilé dé ilé. (Mátíù 10:11-13; Ìṣe 5:42; 20:20) Àwọn ajíhìnrere ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní yẹn ní àwọn agbègbè tí wọ́n ti ń wàásù. (Mátíù 10:5, 6; 2 Kọ́ríńtì 10:13) Bákan náà lónìí, a ṣètò iṣẹ́ ìwàásù wa dáadáa, a sì fún ìjọ kọ̀ọ̀kan ní ibi tí wọ́n á ti máa wàásù. Èyí jẹ́ ká lè máa tẹ̀ lé àṣẹ tí Jésù pa fún wa pé ká “wàásù fún àwọn èèyàn ká sì jẹ́rìí kúnnákúnná.”—Ìṣe 10:42.
À ń sapá láti wàásù fún àwọn èèyàn láwọn ibi tá a ti lè rí wọn. Jésù tún fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ bó ṣe wàásù níbi táwọn èèyàn máa ń wà, irú bí etíkun tàbí nídìí kànga àdúgbò. (Máàkù 4:1; Jòhánù 4:5-15) Àwa náà máa ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì láwọn ibi tá a ti lè ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, níbi iṣẹ́, nínú ọgbà ìgbafẹ́ tàbí lórí fóònù. A tún máa ń wàásù fún àwọn aládùúgbò wa, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ọmọ ilé ìwé wa àtàwọn mọ̀lẹ́bí wa nígbà tí àyè rẹ̀ bá yọ. Gbogbo àwọn ohun tí à ń ṣe yìí ti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn kárí ayé gbọ́ “ìhìn rere ìgbàlà.”—Sáàmù 96:2.
Ta lo rò pé o lè sọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àti ohun tí ìyẹn máa ṣe fún wọn lọ́jọ́ iwájú? Má ṣe fi ọ̀rọ̀ ìtùnú yìí mọ sọ́dọ̀ ara rẹ nìkan. Sọ ọ́ fún wọn láìjáfara!
-
“Ìhìn rere” wo la gbọ́dọ̀ kéde?
-
Báwo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?