Ẹ̀KỌ́ 18
Báwo La Ṣe Ń Ṣèrànwọ́ fún Àwọn Ará Wa Tí Àjálù Bá?
Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣètò ìrànwọ́ tó máa mú kí ara tu àwọn ará wa tí àjálù bá. Irú ìrànwọ́ bẹ́ẹ̀ máa ń fi hàn pé ìfẹ́ tòótọ́ ló wà láàárín wa. (Jòhánù 13:34, 35; 1 Jòhánù 3:17, 18) Àwọn ìrànlọ́wọ́ wo la máa ń ṣe?
A máa ń fowó ṣèrànwọ́. Nígbà tí ìyàn ńlá mú ní Jùdíà, àwọn tó kọ́kọ́ di Kristẹni ní ìlú Áńtíókù fi owó ránṣẹ́ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ará wọn ní Jùdíà. (Ìṣe 11:27-30) Lọ́nà kan náà, tá a bá gbọ́ pé nǹkan nira fún àwọn ará wa láwọn apá ibì kan láyé, a máa ń fi owó ṣètìlẹyìn láwọn ìjọ wa, kí wọ́n lè fi pèsè àwọn nǹkan tí àwọn ará náà nílò lásìkò tí nǹkan nira fún wọn.—2 Kọ́ríńtì 8:13-15.
A máa ń pèsè ohun tí wọ́n nílò. Àwọn alàgbà tó bá wà níbi tí àjálù ti ṣẹlẹ̀ máa ń wá ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ kàn, láti rí i pé gbogbo wọn wà lálàáfíà. Ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó ètò ìrànwọ́ máa ń ṣètò oúnjẹ, omi tó mọ́, aṣọ, ilé gbígbé, wọ́n sì ń bójú tó ìlera àwọn tọ́rọ̀ kàn. Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n mọ iṣẹ́ tí wọ́n lè fi ṣàtúnṣe ibi tí àjálù bà jẹ́, máa ń ná owó ara wọn láti lọ ṣèrànwọ́ fún àwọn tí àjálù bá tàbí kí wọ́n lọ tún àwọn ilé àti Gbọ̀ngàn Ìjọba tó bà jẹ́ ṣe. Bá a ṣe wà níṣọ̀kan nínú ètò wa àti ìrírí tá a ti ní bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ máa ń jẹ́ ká lè tètè kóra jọ láti ṣèrànwọ́ nígbà ìṣòro. Bí a ṣe ń ṣèrànwọ́ fún “àwọn tó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́,” la tún ń ṣèrànwọ́ fún àwọn míì tó bá ṣeé ṣe, láìka ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe sí.—Gálátíà 6:10.
A máa ń fi Ìwé Mímọ́ tu àwọn èèyàn nínú. Àwọn tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ sí máa ń nílò ìtùnú gan-an. Nírú àkókò bẹ́ẹ̀, a máa ń rí okun gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà, “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.” (2 Kọ́ríńtì 1:3, 4) Inú wa máa ń dùn láti sọ àwọn ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì fún àwọn tí ìdààmú bá, à ń mú un dá wọn lójú pé láìpẹ́ Ìjọba Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo àjálù tó ń fa ìrora àti ìjìyà bá aráyé.—Ìfihàn 21:4.
-
Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti máa tètè ṣèrànwọ́ nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀?
-
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo la lè fi sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn tó yè bọ́ nínú àjálù?