Ẹ̀KỌ́ 6
Àǹfààní Wo La Máa Rí Tá A Bá Ń Bá Àwọn Tá A Jọ Jẹ́ Kristẹni Ṣọ̀rẹ́?
A máa ń lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ déédéé, àní tó bá tiẹ̀ gba pé ká gba àárín igbó kìjikìji kọjá tàbí ká fara da ojú ọjọ́ tí kò bára dé. Láìka àwọn ìṣòro tá a ní sí àti àárẹ̀ lẹ́yìn iṣẹ́ ojoojúmọ́, kí nìdí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi máa ń rí i pé a wà pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́?
Ó ń gbé wa ró. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ nípa àwọn tá a jọ ń pàdé nínú ìjọ, ó sọ pé, ‘Ẹ jẹ́ ká gba ti ara wa rò.’ (Hébérù 10:24) Ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí “ká ronú dáadáa nípa,” ìyẹn ni pé ká mọ ara wa. Torí náà, ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì yìí ń rọ̀ wá pé ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì jẹ wá lọ́kàn. Bá a ṣe túbọ̀ ń mọ àwọn ìdílé míì tá a jọ jẹ́ Kristẹni, a máa rí i pé àwọn kan lára wọn ti borí àwọn ìṣòro tó jọ tiwa, wọ́n sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí tiwa.
Ó ń jẹ́ ká ní àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà. Ní àwọn ìpàdé wa, a máa ń pé jọ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa, wọn kì í ṣe ẹni tá a mọ̀ lásán, ọ̀rẹ́ àtàtà ni wọ́n jẹ́. Láwọn ìgbà míì, a jọ máa ń ṣe eré ìnàjú tó dáa. Àǹfààní wo ni irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ máa ń ṣe wá? Ó ń jẹ́ ká túbọ̀ mọyì ara wa, ó sì ń jẹ́ kí ìfẹ́ tó wà láàárín wa pọ̀ sí i. Tí àwọn ọ̀rẹ́ wa yìí bá wá níṣòro, a máa ń tètè ràn wọ́n lọ́wọ́ torí pé wọ́n ti di ọ̀rẹ́ wa àtàtà. (Òwe 17:17) Tá a bá ń fi gbogbo àwọn ará ìjọ ṣe ọ̀rẹ́, à ń fi hàn pé à ń “ṣìkẹ́ ara” wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.—1 Kọ́ríńtì 12:25, 26.
A rọ̀ ẹ́ pé kó o mú àwọn tó ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lọ́rẹ̀ẹ́. Wàá rí irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Jọ̀ọ́, má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun dí ẹ lọ́wọ́ láti dara pọ̀ mọ́ wa.
-
Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń wà pẹ̀lú àwọn ará ní àwọn ìpàdé wa?
-
Ìgbà wo lo máa bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí ìpàdé ìjọ wa?