Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

INDONÉṢÍÀ

Àpéjọ Mánigbàgbé Kan

Àpéjọ Mánigbàgbé Kan

NÍ AUGUST 15 sí 18 ọdún 1963, àpéjọ àgbáyé àkọ́kọ́ wáyé lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà. Àkọlé àpéjọ náà ní “Ìhìn Rere Àìnípẹ̀kun.” Ìlú Bandung tó wà ní West Java ni wọ́n sì ti ṣe é. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn akéde láti gbogbo agbègbè Indonéṣíà ló pésẹ̀ síbẹ̀, a sì tún rí àwọn méjìlélọ́gọ́fà [122] láti àwọn orílẹ̀-èdè míì.

Nǹkan ò rọrùn rárá nígbà tí wọ́n ń múra bí wọ́n ṣe fẹ́ ṣe àpéjọ náà. Ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la ní láti wá ibòmíì tá a ti máa ṣe àpéjọ nítorí ayẹyẹ Ọjọ́ Òmìnira orílẹ̀-èdè Indonéṣíà tó bọ́ sí ìgbà àpéjọ náà. Ohun míì tó tún ṣẹlẹ̀ ni ọrọ̀ ajé tó dẹ́nu kọlẹ̀ èyí tó mú kí ìjọba sọ àwọn nǹkan di ọ̀wọ́n gógó. Àní, ìlọ́po mẹ́rin lowó ọkọ̀ fi wọ́n ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Síbẹ̀, àwọn ará wá bí wọ́n á ṣe débẹ̀ láìwọ mọ́tò. Ńṣe ni arákùnrin kan fẹsẹ̀ rìn fún odindi ọjọ́ mẹ́fà. Ọjọ́ márùn-ùn sì làwọn ará tí ó tó ọgọ́rin [70] fi rìnrìn àjò lójú omi láti ìlú Sulawesi. Bẹ́ẹ̀, ọkọ̀ ojú omi ọ̀hún kún fọ́fọ́, kò sì ní ìbòrí.

Ìdùnnú ṣubú layọ̀ fáwọn ará Indonéṣíà tó wá sí àpéjọ náà nígbà tí wọ́n pàdé àwọn ará tó wá láti àwọn orílẹ̀-èdè míì. Orí wọn tún wú nígbà tí wọ́n rí Arákùnrin Frederick Franz àti Grant Suiter tó jẹ́ ara ìgbìmọ̀ olùdarí. Ọ̀kan lára wọn sọ pe: “Ṣe ni inú àwọn ará ń dùn ṣìnkìn, wọ́n ń rẹ̀rín, wọ́n sì ń yọ̀.”

Ó lé ní ọgọ́rùn-ún méje àti àádọ́ta [750] èèyàn tó wá sí àpéjọ náà, àwọn mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [34] ló sì ṣe ìrìbọmi. Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Ronald Jacka sọ pé: “Àpéjọ mánigbàgbé yìí mú kí ọ̀pọ̀ olùfìfẹ́hàn sọ òtítọ́ di tiwọn, ó sì ta àwọn ará tó ń gbé ní Indonéṣíà jí láti fìtara ṣiṣẹ́ Ọlọ́run.”

Arákùnrin Ronald Jacka (lápá ọ̀tún) ń sọ àsọyé ní Àpéjọ “Ìhìn Rere Àìnípẹ̀kun” lọ́dún 1963, ẹnì kejì sì ń ṣe ògbufọ̀