ORÍ 130
Ó Fa Jésù Lé Wọn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Lọ Pa Á
MÁTÍÙ 27:31, 32 MÁÀKÙ 15:20, 21 LÚÙKÙ 23:24-31 JÒHÁNÙ 19:6-17
-
PÍLÁTÙ GBÌYÀNJÚ LÁTI TÚ JÉSÙ SÍLẸ̀
-
WỌ́N DÁ JÉSÙ LẸ́BI, WỌ́N SÌ MÚ UN LỌ SÍBI TÍ WỌ́N TI FẸ́ PA Á
Onírúurú nǹkan ni wọ́n ti fojú Jésù rí, wọ́n ti hùwà ìkà sí i, wọ́n sì ti kàn án lábùkù. Pàbó ni gbogbo ìsapá Pílátù láti tú u sílẹ̀ ń já sí, kò tiẹ̀ tu irun kan lára àwọn olórí àlùfáà àtàwọn alátìlẹyìn wọn. Ohun tí wọ́n ṣáà fẹ́ ni pé kí Jésù kú, torí náà wọ́n ń kígbe pé: “Kàn án mọ́gi! Kàn án mọ́gi!” Àmọ́ Pílátù dá wọn lóhùn pé: “Ẹ mú un fúnra yín, kí ẹ sì pa á, torí èmi ò rí i pé ó jẹ̀bi kankan.”—Jòhánù 19:6.
Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn ò rí ẹ̀sùn kankan tí wọ́n lè fi kan Jésù pé ó rú òfin ìjọba, torí náà Pílátù ò lè dájọ́ ikú fún un. Àmọ́ ṣé wọ́n lè rí ẹ̀sùn fi kàn án pé ó rú Òfin Ọlọ́run? Wọ́n wá ronú kan ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án níwájú Sàhẹ́ndìrìn pé ó ń sọ̀rọ̀ òdì. Wọ́n ní: “A ní òfin kan, bí òfin yẹn sì ṣe sọ, ó yẹ kó kú, torí ó pe ara rẹ̀ ní ọmọ Ọlọ́run.” (Jòhánù 19:7) Ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa sọ̀rọ̀ yìí létí Pílátù nìyẹn.
Ni Pílátù bá pa dà sínú ààfin rẹ̀ kó lè wá bó ṣe máa tú Jésù sílẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí Pílátù máa ronú nípa bí wọ́n ṣe fìyà jẹ Jésù àtohun tí ìyàwó rẹ̀ sọ pé òun rí lójú àlá nípa Jésù. (Mátíù 27:19) Èwo wá ni ẹ̀sùn tí wọ́n tún fi kàn án yìí, tí wọ́n ní ó ń pe ara ẹ̀ ní “ọmọ Ọlọ́run”? Lóòótọ́ Pílátù mọ̀ pé Gálílì ni Jésù ti wá. (Lúùkù 23:5-7) Síbẹ̀ ó béèrè lọ́wọ́ Jésù pé: “Ibo lo ti wá?” (Jòhánù 19:9) Àbí ṣe ni Pílátù ń rò ó pé Jésù ti wà láyé nígbà kan rí, tí Ọlọ́run wá pa dà rán an wá sáyé?
Jésù ti sọ fún Pílátù tẹ́lẹ̀ pé ọba lòun àti pé Ìjọba òun kì í ṣe apá kan ayé yìí. Jésù mọ̀ pé kò pọn dandan kóun tún máa ṣàlàyé ọ̀rọ̀ yẹn, torí náà kò sọ nǹkan kan. Ṣe ló dà bíi pé Jésù kan Pílátù lábùkù bí ò ṣe sọ̀rọ̀ yẹn, ni Pílátù bá fi ìgbéraga sọ pé: “Ṣé o ò fẹ́ bá mi sọ̀rọ̀ ni? Àbí o ò mọ̀ pé mo ní àṣẹ láti tú ọ sílẹ̀, mo sì tún ní àṣẹ láti pa ọ́?”—Jòhánù 19:10.
Jésù wá sọ pé: “O ò lè ní àṣẹ kankan lórí mi àfi tí a bá fún ọ láṣẹ látòkè. Ìdí nìyẹn tí ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin tó fi mí lé ọ lọ́wọ́ fi tóbi jù.” (Jòhánù 19:11) Kì í ṣe ẹnì kan péré ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ ọ̀rọ̀ yẹn. Ohun tó sọ fi hàn pé Káyáfà, àwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ àti Júdásì Ìsìkáríọ́tù ló ní lọ́kàn, ẹ̀bi gbogbo wọn pọ̀ ju ti Pílátù lọ.
Ọ̀rọ̀ Jésù jọ Pílátù lójú, ó rí i pé ọkàn ẹ̀ balẹ̀, ó wá ń bẹ̀rù pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló ti wá lóòótọ́. Torí náà, Pílátù ń wá bó ṣe máa tú Jésù sílẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Làwọn Júù bá tún mẹ́nu ba ohun míì tó dẹ́rù ba Pílátù. Wọ́n halẹ̀ mọ́ ọn pé: “Tí o bá tú ọkùnrin yìí sílẹ̀, o kì í ṣe ọ̀rẹ́ Késárì. Ṣe ni gbogbo ẹni tó bá pe ara rẹ̀ ní ọba ń ta ko Késárì.”—Jòhánù 19:12.
Ni gómìnà yìí bá mú Jésù wá síta lẹ́ẹ̀kan sí i, ó jókòó sórí ìjókòó ìdájọ́, ó wá sọ fáwọn èèyàn náà pé: “Ẹ wò ó! Ọba yín nìyí!” Àmọ́ ọ̀rọ̀ yìí ò tíì sú àwọn Júù yẹn. Ṣe ni wọ́n ń kígbe pé: “Mú un lọ! Mú un lọ! Kàn án mọ́gi!” Pílátù wá bi wọ́n pé: “Ṣé kí n pa ọba yín ni?” Lóòótọ́, ọjọ́ pẹ́ tí ìjọba Róòmù ti ń ni àwọn Júù lára, ìyẹn ò sì tẹ́ wọn lọ́rùn, síbẹ̀ gbogbo ẹnu làwọn olórí àlùfáà yìí fi sọ pé: “A ò ní ọba kankan àfi Késárì.”—Jòhánù 19:14, 15.
Torí pé ẹ̀rù ń ba Pílátù, ó gbà láti ṣe ohun táwọn Júù náà ń béèrè, ló bá ní kí wọ́n lọ pa Jésù. Àwọn ọmọ ogun wá bọ́ aṣọ ìlékè rírẹ̀dòdò tó wà lọ́rùn rẹ̀, wọ́n sì wọ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ fún un. Ni wọ́n bá mú Jésù lọ síbi tí wọ́n ti fẹ́ pa á, wọ́n sì fi dandan mú un pé kó gbé òpó igi oró rẹ̀.
Jésù ò tíì fojú ba oorun látàárọ̀ Thursday, onírúurú nǹkan ni wọ́n sì ti fojú ẹ̀ rí. Ilẹ̀ tún ti mọ́ láàárọ̀ Friday Nísàn 14. Torí náà, bó ṣe ń gbé òpó igi oró náà lọ, agbára ẹ̀ tán. Àwọn ọmọ ogun wá rí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Símónì tó wá láti Kírénè nílẹ̀ Áfíríkà tó ń kọjá lọ, wọ́n sì fipá mú un pé kó bá Jésù gbé òpó igi oró náà. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń tẹ̀
lé wọn nígbà tí wọ́n ń mú Jésù lọ, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù yìí kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn kan lára àwọn èèyàn náà, wọn wá bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún.Ni Jésù bá sọ fáwọn obìnrin tó ń sunkún pé: “Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù, ẹ má sunkún torí mi mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ sunkún torí ara yín àti àwọn ọmọ yín; torí ẹ wò ó! ọjọ́ ń bọ̀ tí àwọn èèyàn máa sọ pé, ‘Aláyọ̀ ni àwọn àgàn, àwọn ilé ọlẹ̀ tí kò bímọ àti àwọn ọmú tí ọmọ kò mu!’ Wọ́n á wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún àwọn òkè ńláńlá pé, ‘Ẹ wó lù wá!’ àti fún àwọn òkè kéékèèké pé, ‘Ẹ bò wá mọ́lẹ̀!’ Tí wọ́n bá ṣe àwọn nǹkan yìí nígbà tí igi ṣì tutù, kí ló máa ṣẹlẹ̀ nígbà tó bá rọ?”—Lúùkù 23:28-31.
Àwọn Júù ni Jésù ń darí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí. Orílẹ̀-èdè yẹn ló dà bí igi tó ti ń kú lọ, àmọ́ torí pé Jésù àtàwọn díẹ̀ kan tí wọ́n nígbàgbọ́ nínú rẹ̀ ṣì wà láàárín àwọn Júù yẹn ló ṣe dà bíi pé igi yẹn ṣì tutù díẹ̀. Nígbà tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ bá kúrò láàárín wọn, wọ́n máa dà bí igi tó ti rọ tí ò ní pẹ́ kú, torí pé Ọlọ́run ti pa wọ́n tì. Àwọn èèyàn yẹn máa sunkún gan-an tí Ọlọ́run bá lo àwọn ọmọ ogun Róòmù láti mú ìdájọ́ rẹ̀ wá sórí wọn.