Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ KẸTA

“Baba Gbogbo Àwọn Tí Wọ́n Ní Ìgbàgbọ́”

“Baba Gbogbo Àwọn Tí Wọ́n Ní Ìgbàgbọ́”

1, 2. Báwo ni àwọn èèyàn ṣe yí pa dà tó sí ti ìgbà ayé Nóà, báwo lèyí sì ṣe rí lára Ábúrámù?

ÁBÚRÁMÙ gbójú sókè, ó bojú wo tẹ́ńpìlì kan tó ga fíofío láàárín ìlú Úrì tó jẹ́ ìlú rẹ̀. * Tẹ́ńpìlì náà jẹ́ ipele-ipele àgbékà tó ní orí ṣóńṣó, tó sì ní ìdí rẹ̀kẹ̀tẹ̀. Àwọn èèyàn tó wà lókè rẹ̀ ń pariwo gèè, èéfín sì ń rú túú níbẹ̀. Àwọn àlùfáà tó ń bọ òṣùpá ló tún ń rúbọ. Fojú inú wo Ábúrámù bó ṣe yíjú pa dà kúrò níbẹ̀, tó mirí, tó sì fajú ro. Bó ṣe ń gba àárín èrò tó wà nígboro kọjá lọ sílé, ó ṣeé ṣe kó máa ronú lórí bí ìbọ̀rìṣà ṣe kún ìlú Úrì yìí. Kó máa rò ó pé, ‘ó mà ṣe o, ẹ wo bí ìbọ̀rìṣà ṣe wá ń gbilẹ̀ láyé láti ìgbà ayé Nóà!’

2 Nígbà tí Nóà àti ìdílé rẹ̀ jáde kúrò nínú áàkì lẹ́yìn Àkúnya Omi, Jèhófà Ọlọ́run ni Nóà rúbọ sí. Jèhófà sì wá mú kí òṣùmàrè fara hàn lójú ọ̀run. (Jẹ́n. 8:20; 9:12-14) Ìjọsìn mímọ́ nìkan ṣoṣo ló wà láyé nígbà yẹn. Ọdún méjì péré lẹ́yìn tí Nóà kú ni wọ́n bí Ábúrámù. Àmọ́ nígbà ayé Ábúrámù, tó jẹ́ ìran kẹwàá sí Nóà, ńṣe ni ìjọsìn mímọ́ túbọ̀ ń ṣọ̀wọ́n bí àwọn èèyàn ṣe ń tàn ká ayé. Òrìṣà ni àwọn èèyàn níbi gbogbo wá ń bọ. Kódà Térà baba Ábúráhámù pàápàá ń lọ́wọ́ sí ìbọ̀rìṣà. Ó ṣeé ṣe kó máa bá wọn ṣe ère.—Jóṣ. 24:2.

Báwo ni Ábúrámù ṣe di àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tó ta yọ?

3. Kí ni Ábúrámù ní, tó túbọ̀ ń hàn kedere bó ṣe ń dàgbà? Kí la sì lè rí kọ́ nínú ìyẹn?

3 Ṣùgbọ́n Ábúrámù yàtọ̀ sí wọn ní tiẹ̀. Bó ṣe ń dàgbà sí i ni ìyàtọ̀ náà túbọ̀ ń ṣe kedere torí ìgbàgbọ́ tó ní nínú Ọlọ́run. Kódà nígbà tó yá, Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti pè é ní “baba gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́”! (Ka Róòmù 4:11.) Ẹ jẹ́ ká wo bí Ábúrámù ṣe dẹni tó ní ìgbàgbọ́ tó ta yọ. Ìyẹn á jẹ́ kí àwa náà mọ ohun tí a lè ṣe tí ìgbàgbọ́ wa yóò fi túbọ̀ lágbára.

Ọwọ́ Tí Àwọn Èèyàn Fi Mú Ìjọsìn Jèhófà Lẹ́yìn Ìkún-Omi

4, 5. Ọ̀dọ̀ ta ló ṣeé ṣe kí Ábúrámù ti mọ̀ nípa Jèhófà? Kí nìdí tá a fi lè gbà pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ látọ̀dọ̀ rẹ̀?

4 Báwo ni Ábúrámù ṣe mọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run? A mọ̀ pé Jèhófà ní àwọn ìránṣẹ́ olóòótọ́ láyé ìgbà yẹn. Ṣémù jẹ́ ọ̀kan lára wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ṣémù kọ́ ni àkọ́bí nínú ọmọ mẹ́ta tí Nóà bí, orúkọ rẹ̀ ni Bíbélì sábà máa ń kọ́kọ́ mẹ́nu kàn nínú wọn. Ó jọ pé ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé ìgbàgbọ́ Ṣémù ta yọ. * Nígbà kan lẹ́yìn Ìkún-omi, Nóà tiẹ̀ pe Jèhófà ní “Ọlọ́run Ṣémù.” (Jẹ́n. 9:26) Ṣémù bọ̀wọ̀ fún Jèhófà, kò sì fi ìsìn mímọ́ ṣeré.

5 Ṣé Ábúrámù wá mọ Ṣémù ni? Ó ṣeé ṣe kó mọ̀ ọ́n. Fojú inú wo Ábúrámù nígbà tó wà lọ́mọdé. Inú rẹ̀ máa dùn gan-an ni láti gbọ́ pé ọ̀kan lára àwọn baba ńlá òun tó ti dàgbà ju irínwó [400] ọdún lọ ṣì wà láàyè! Ṣémù fojú rí bí ìwà ibi ṣe gbilẹ̀ láyé ṣáájú Ìkún-omi, ìṣojú rẹ̀ sì ni Àkúnya Omi palẹ̀ gbogbo ìwà ibi wọ̀nyẹn mọ́. Ìṣojú rẹ̀ náà ni àwọn èèyàn ń gbilẹ̀ tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í di onírúurú orílẹ̀-èdè. Ó wà láyé ní gbogbo ìgbà tí Nímírọ́dù ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, tí òun àti àwọn èèyàn ìgbà yẹn ń kọ́ Ilé Gogoro Bábélì. Àmọ́ Ṣémù olóòótọ́ kò bá wọn lọ́wọ́ sí i. Nígbà tí Jèhófà wá da èdè àwọn tó ń kọ́ ilé yẹn rú, èdè tí gbogbo èèyàn ń sọ bọ̀ látẹ̀yìn wá ni Ṣémù àti ìdílé rẹ̀ ṣì ń sọ ní tiwọn, ìyẹn èdè tí Nóà sọ. Inú ìdílé Ṣémù yìí sì ni Ábúrámù ti wá. Ó dájú pé bí Ábúrámù ṣe ń dàgbà, á túbọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún Ṣémù gan-an. Yàtọ̀ síyẹn pàápàá, Ṣémù ṣì wà láàyè ní èyí tó pọ̀ jù nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tí Ábúrámù lò láyé. Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Ṣémù ni Ábúrámù tí mọ̀ nípa Jèhófà.

Ábúrámù kórìíra ìbọ̀rìṣà tó gbilẹ̀ ní ìlú Úrì

6. (a) Báwo ni Ábúrámù ṣe fi ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà Àkúnya Omi kọ́gbọ́n? (b) Báwo ni ìgbé ayé Ábúrámù àti Sáráì ṣe rí?

6 Bó ti wù kó rí, Ábúrámù fi ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà Àkúnya Omi kọ́gbọ́n. Ó sapá gan-an kó lè bá Ọlọ́run rìn bíi ti Nóà. Ìdí nìyẹn tó fi kórìíra ìbọ̀rìṣà, tó sì dá yàtọ̀ láàárín àwọn ará Úrì, bóyá tó tiẹ̀ tún dá yàtọ̀ nínú ìdílé wọn pàápàá. Ó sì wá fẹ́ aya rere kan tó ń tì í lẹ́yìn. Sáráì ni orúkọ rẹ̀. * Ó rẹwà gan-an, ìgbàgbọ́ tó ní nínú Jèhófà náà sì tún ṣàrà ọ̀tọ̀. Lóòótọ́ wọn kò tíì bímọ, àmọ́ wọ́n ń láyọ̀ bí wọ́n ṣe jọ ń sin Jèhófà. Àwọn náà ló tọ́ Lọ́ọ̀tì ọmọ ẹ̀gbọ́n Ábúrámù tí kò ní ìyá àti bàbá mọ́.

7. Báwo ni àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ábúrámù?

7 Ábúrámù kò fìgbà kankan pa Jèhófà tì, kó wá máa bọ òrìṣà ìlú Úrì. Òun àti Sáráì jẹ́ kí tiwọn yàtọ̀ láàárín àwọn abọ̀rìṣà tí wọ́n ń gbé. Irú ẹ̀mí yẹn ló yẹ kí àwa náà ní tá a bá fẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa jẹ́ ojúlówó ìgbàgbọ́. A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí tiwa náà yàtọ̀. Jésù sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun kò ní jẹ́ “apá kan ayé,” àti pé ìyẹn máa jẹ́ kí ayé kórìíra wọn. (Ka Jòhánù 15:19.) Tó bá ń dùn ọ́ pé ìdílé rẹ tàbí àwọn ará ìlú rẹ kọ̀ ọ́ torí pé o ń sin Jèhófà, rántí pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn bíi Ábúrámù àti Sáráì. Ṣe ló fi hàn pé ìwọ náà ń bá Ọlọ́run rìn bíi tiwọn.

“Jáde Kúrò ní Ilẹ̀ Rẹ”

8, 9. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Ábúrámù tí kò lè gbàgbé láé? (b) Kí ni Jèhófà sọ fún Ábúrámù?

8 Lọ́jọ́ kan, ohun kan ṣẹlẹ̀ sí Ábúrámù tí kò lè gbàgbé láé. Kí ló ṣẹlẹ̀? Jèhófà Ọlọ́run bá a sọ̀rọ̀! Bíbélì kò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ bó ṣe ṣẹlẹ̀, àmọ́ ó sọ pé “Ọlọ́run ògo” fara han ọkùnrin olóòótọ́ yìí. (Ka Ìṣe 7:2, 3.) Bóyá ṣe ni Ọlọ́run rán áńgẹ́lì sí Ábúrámù, tó fi wá rí fìrífìrí ògo Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run tó kàmàmà. A lè fojú inú wo bó ṣe máa wú Ábúrámù lórí tó láti rí bí Ọlọ́run alààyè ṣe yàtọ̀ pátápátá sí àwọn òrìṣà aláìlẹ́mìí tí àwọn èèyàn ń bọ nígbà náà.

9 Kí ni Jèhófà sọ fún Ábúrámù? Ohun tó sọ ni pé: “Jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, kí o sì wá sí ilẹ̀ tí èmi yóò fi hàn ọ́.” Jèhófà kò sọ ilẹ̀ tó ní lọ́kàn fún Ábúrámù, ó kàn lóun máa fi ilẹ̀ yẹn hàn án ni. Ṣùgbọ́n Ábúrámù ní láti kọ́kọ́ fi ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ àti àwọn ìbátan rẹ̀ sílẹ̀ ná. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìdílé ṣe pàtàkì gan-an lójú àwọn èèyàn ilẹ̀ Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn látijọ́. Nǹkan burúkú gbáà ni wọ́n sábà máa ń kà á sí téèyàn bá kó kúrò lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀, tó wá lọ ń gbé lọ́nà jíjìn. Kódà àwọn kan gbà pé ìyẹn burú ju kéèyàn kú lọ!

10. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Ábúrámù àti Sáráì fi ọ̀pọ̀ nǹkan du ara wọn bí wọ́n ṣe fi Úrì ìlú wọn sílẹ̀?

10 Ábúrámù tún fi ọ̀pọ̀ nǹkan du ara rẹ̀ bó ṣe fẹ́ kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀. Ẹ̀rí fi hàn pé ìlú ọlọ́rọ̀, tí èrò pọ̀ sí gan-an ni ìlú Úrì. (Wo àpótí náà  “Ìlú Tí Ábúrámù àti Sáráì Fi Sílẹ̀.”) Nígbà tí àwọn awalẹ̀pìtàn walẹ̀ ìlú Úrì àtijọ́, wọ́n rí i pé àwọn ilé tí wọ́n kọ́ ringindin tó sì ní àwọn ohun amáyédẹrùn wà níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ilé náà ní yàrá méjìlá tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n ṣe fún ìdílé àtàwọn ìránṣẹ́ wọn, wọ́n sì ṣe àwọn yàrá náà yí ká àgbàlá tí wọ́n fi òkúta tẹ́. Orísun omi àtọwọ́dá, ilé ìyàgbẹ́ àti ibi tí omi ẹ̀gbin ń gbà kọjá wà lára àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe sí àwọn ilé tó wà níbẹ̀. Ẹ má sì gbàgbé pé Ábúrámù àti Sáráì ti di àgbàlagbà, torí ó jọ pé Ábúrámù ti lé ní ẹni àádọ́rin ọdún, Sáráì náà sì ti lé ní ọgọ́ta ọdún. Ó dájú pé, gẹ́gẹ́ bí ọkọ rere, Ábúrámù kò ní fẹ́ kí ìyà jẹ Sáráì lọ́nàkọnà. Ìwọ fojú inú wo bí àwọn méjèèjì a ṣe máa fọ̀rọ̀ wérọ̀ nípa ohun tí Ọlọ́run ní kí Ábúrámù ṣe yìí, tí wọ́n á máa jíròrò àwọn ìbéèrè tí wọ́n bá ní àtàwọn nǹkan míì tó bá ń jẹ wọ́n lọ́kàn. Láìsí àní-àní, inú Ábúrámù yóò dùn gan-an nígbà tí Sáráì gbà pé kí àwọn ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ! Ó gbà tinútinú bíi ti Ábúrámù láti fi ìlú wọn tí nǹkan ti rọ̀ ṣọ̀mù sílẹ̀.

11, 12. (a) Ìmúrasílẹ̀ àti àwọn ìpinnu wo ni wọ́n máa ní láti ṣe kí wọ́n tó kúrò ní ìlú Úrì? (b) Sọ ohun tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ nígbà tí ilẹ̀ mọ́ lọ́jọ́ tí wọ́n fẹ́ gbéra ìrìn àjò náà.

11 Bí Ábúrámù àti Sáráì ṣe wá gbà láti lọ, ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n máa ní láti ṣe. Wọ́n máa ní láti kó ọ̀pọ̀ ẹrù, kí wọ́n dì wọ́n dáadáa, kí wọ́n sì ṣètò bí wọ́n ṣe máa rin ìrìn àjò náà. Wọ́n á máa rò ó pé kí ni kí àwọn mú dání nínú ìrìn àjò tí àwọn ò mọ òpin rẹ̀ yìí, kí sì ni kí àwọn fi sílẹ̀? Wọ́n tún ní láti pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe nípa ìdílé wọn, àwọn ẹrú wọn àti ojúlùmọ̀ wọn gbogbo, pàápàá Térà bàbá Ábúrámù tó ti darúgbó. Wọ́n pinnu pé Térà yóò bá àwọn lọ, kí àwọn lè máa tọ́jú rẹ̀ bí àwọn ṣe ń lọ. Ó jọ pé tinútinú ló fi gbà láti bá wọn lọ, torí òun tó jẹ́ baba ńlá nínú ìdílé náà ni Bíbélì sọ pé ó kó ìdílé rẹ̀ jáde kúrò ní ìlú Úrì. Ó ní láti jẹ́ pé Térà ti jáwọ́ nínú ìbọ̀rìṣà. Lọ́ọ̀tì ọmọ ẹ̀gbọ́n Ábúrámù náà sì tẹ̀ lé wọn.—Jẹ́n. 11:31.

12 Nígbà tó yá, ilẹ̀ ọjọ́ tí wọ́n fẹ́ gbéra ìrìn àjò náà mọ́. Fojú inú wò wọ́n bí wọ́n ṣe ń kóra jọ lọ́wọ̀ọ̀wọ́ sẹ́yìn odi ìlú Úrì tí omi yí ká. Ẹrù ti wà lórí àwọn ràkúnmí àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, wọ́n ti kó ọ̀wọ́ ẹran ọ̀sìn wọn jọ. Olúkúlùkù nínú ìdílé náà ti wà ní sẹpẹ́ ní àyè tirẹ̀, wọ́n sì múra láti gbéra. * Bóyá gbogbo wọ́n wá yíjú sí Ábúrámù, wọ́n ń retí pé kó sọ fún àwọn pé ìlọ yá! Níkẹyìn, Ábúrámù sọ pé ó ti yá. Ni wọ́n bá gbéra, wọ́n sì fi ìlú Úrì sílẹ̀ pátápátá.

13. Báwo ni ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní ṣe ń fi hàn pé àwọn ní irú ẹ̀mí tí Ábúrámù àti Sáráì ní?

13 Lóde òní, ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Jèhófà ló ń ṣí lọ síbi tí àwọn tó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ò ti pọ̀ láti lọ sìn níbẹ̀. Àwọn kan kọ́ èdè míì kó lè ṣeé ṣe fún wọn láti máa wàásù fún ọ̀pọ̀ èèyàn. Àwọn míì sì ń gbìyànjú láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù láwọn ọ̀nà míì tí kò fi bẹ́ẹ̀ rọ̀ wọ́n lọ́rùn tẹ́lẹ̀. Irú nǹkan tí àwọn wọ̀nyí ṣe sábà máa ń gba pé kí wọ́n fi àwọn ohun ìní tara kan du ara wọn. Ẹ̀mí tí wọ́n ní yìí dáa gan-an ni! Ó fi hàn pé wọ́n ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ábúrámù àti Sáráì. Tí àwa náà bá nígbàgbọ́ bíi tiwọn, kí ó dá wa lójú pé ìlọ́po-ìlọ́po ohun tí a bá ṣe fún Jèhófà ló máa fi san wá lẹ́san. Ó dájú pé kì í kùnà láti san ẹ̀san fún àwọn tó bá ṣe iṣẹ́ ìgbàgbọ́. (Héb. 6:10; 11:6) Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ san ẹ̀san fún Ábúrámù?

Wọ́n Sọdá Odò Yúfírétì

14, 15. Báwo ni ìrìn àjò Ábúrámù àtàwọn èèyàn rẹ̀ ṣe rí láti Úrì sí Háránì? Kí ló sì lè jẹ́ ìdí tí wọ́n fi dúró sí Háránì fúngbà díẹ̀?

14 Díẹ̀díẹ̀, ìrìn-àjò náà bẹ̀rẹ̀ sí í mọ́ gbogbo wọn lára. A lè fojú inú wo bí Ábúrámù àti Sáráì yóò ṣe máa rìn fúngbà díẹ̀, tí wọ́n á tún gun ẹran ọ̀sìn wọn fúngbà díẹ̀. Wọ́n á máa fọ̀rọ̀ wérọ̀ bí wọ́n ṣe ń lọ, èèyàn á sì máa gbọ́ ìró àwọn ṣaworo ara okùn ìjánu àwọn ẹran ọ̀sìn wọn. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ rìnrìn àjò rí lára wọn dẹni tó mọ gbogbo àpadé-àludé bí wọ́n ṣe ń pàgọ́ àti bí wọ́n ṣe ń tú u kíá, títí kan bí wọ́n ṣe máa ran Térà arúgbó lọ́wọ́ tá a fi lè jókòó tí ara á sì tù ú lórí ràkúnmí tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó máa gbé e. Wọ́n ń gba ọ̀nà ẹ̀gbẹ́ Odò Yúfírétì lọ síhà àríwá ìwọ̀ oòrùn. Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ ni wọ́n túbọ̀ ń rìn jìnnà réré sí ìlú ìbílẹ̀ wọn.

15 Lẹ́yìn tí wọ́n ti rin ìrìn àjò ẹgbẹ̀rún kìlómítà ó dín ogójì [960], wọ́n débi àwọn àgọ́ rubutu tí wọ́n ń kọ́ pọ̀ mọ́ra ní ìlú Háránì. Ìlú ọlọ́rọ̀ yìí wà ní ìkòríta ọ̀nà àwọn oníṣòwò tó ti ìlà oòrùn lọ sí ìwọ̀ oòrùn. Ìdílé yìí wá dúró fúngbà díẹ̀ níbẹ̀. Bóyá torí pé Térà ti darúgbó débi pé agbára rẹ̀ ò gbé ìrìn àjò náà mọ́.

16, 17. (a) Májẹ̀mú wo ló mú inú Ábúrámù dùn? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe bù kún Ábúrámù nígbà tó wà ní Háránì?

16 Nígbà tó yá, Térà kú ní ẹni igba ọdún ó lé márùn-ún [205]. (Jẹ́n. 11:32) Jèhófà tún bá Ábúrámù sọ̀rọ̀ lásìkò tí bàbá rẹ̀ kú yìí, ìyẹn sì tù ú nínú gan-an. Jèhófà wá tún ohun tó ti sọ fún un tẹ́lẹ̀ ní ìlú Úrì sọ, ó sì ṣe àwọn ìlérí míì fún un. Ó ní Ábúrámù yóò di “orílẹ̀-èdè ńlá,” àti pé gbogbo ìdílé ayé yóò rí ìbùkún gbà nípasẹ̀ rẹ̀. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 12:2, 3.) Bí Ọlọ́run ṣe tún wá fìdí májẹ̀mú tó ti bá a dá múlẹ̀ yìí, inú rẹ̀ dùn, ló bá gbéra ó sì ń bá ìrìn àjò náà lọ.

17 Lọ́tẹ̀ yìí, àwọn nǹkan tí wọ́n ní láti kó pọ̀ jù ti tẹ́lẹ̀ lọ torí Jèhófà ti bù kún Ábúrámù gan-an nígbà tó wà ní Háránì. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ó mẹ́nu kan “gbogbo ẹrù tí wọ́n ti kó jọ rẹpẹtẹ àti àwọn ọkàn tí wọ́n ti ní ní Háránì.” (Jẹ́n. 12:5) Ó ṣe tán, kí Ábúrámù tó lè di odindi orílẹ̀-èdè, ó ní láti ní dúkìá àti ìránṣẹ́ rẹpẹtẹ, ìyẹn ni pé yóò ní agboolé ńlá. Ìgbà gbogbo kọ́ ni Jèhófà máa ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ọrọ̀ o, àmọ́ ó dájú pé ó máa ń fún wọ́n ní ohunkóhun tí wọ́n bá nílò láti lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ní báyìí tí Jèhófà ti wá ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan fún Ábúrámù, ó kó àwọn èèyàn rẹ̀, wọ́n tún tẹ̀ síwájú nínú ìrìn àjò wọn lọ sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.

Ọ̀pọ̀ ìpèníjà ni Ábúrámù àti Sáráì ní bí wọ́n ṣe fi ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ ìlú Úrì sílẹ̀

18. (a) Ọjọ́ wo nínú ìrìn àjò Ábúrámù, ló jẹ́ ọjọ́ pàtàkì nínú ìtàn àjọṣe Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn èèyàn Rẹ̀? (b) Àwọn nǹkan pàtàkì míì wo ló tún wáyé ní àyájọ́ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Nísàn lẹ́yìn ìgbà náà? (Wo àpótí náà “Ọjọ́ Pàtàkì Nínú Ìtàn Bíbélì.”)

18 Lẹ́yìn ìrìn àjò ọjọ́ mélòó kan láti Háránì wọ́n dé Kákémíṣì. Ibẹ̀ ni àwọn arìnrìn àjò ti sábà máa ń sọdá Odò Yúfírétì. Ó ṣeé ṣe kí ọjọ́ tó débẹ̀ yẹn jẹ́ ọjọ́ pàtàkì nínú ìtàn àjọṣe Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn èèyàn Rẹ̀. Ẹ̀rí fi hàn pé ọdún 1943 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, lọ́jọ́ kẹrìnlá oṣù tí wọ́n wá ń pè ní Nísàn lẹ́yìn ìgbà náà, ni Ábúrámù kó àwọn èèyàn rẹ̀ sọdá odò yìí. (Ẹ́kís. 12:40-43) Ilẹ̀ tí Jèhófà ṣèlérí pé òun máa fi han Ábúrámù wá lọ salalu níhà gúúsù ibi tí wọ́n wà. Ọjọ́ yẹn ni májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúrámù dá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.

19. Kí ni Jèhófà mẹ́nu bà nínú ìlérí tó ṣe fún Ábúrámù? Kí ni ìlérí yẹn lè mú kí Ábúrámù ronú kàn?

19 Bí Ábúrámù ṣe ń la ilẹ̀ náà kọjá lọ síhà gúúsù, òun àti àwọn tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò dúró lẹ́bàá àwọn igi ńlá Mórè nítòsí ìlú Ṣékémù. Jèhófà sì tún bá Ábúrámù sọ̀rọ̀ níbẹ̀. Nígbà tí Ọlọ́run ń ṣe ìlérí fún un lọ́tẹ̀ yìí, ó mẹ́nu bà á pé irú-ọmọ rẹ̀ ni yóò ni ilẹ̀ náà. Àbí Ábúrámù á tiẹ̀ ronú kan àsọtẹ́lẹ̀ tí Jèhófà sọ ní ọgbà Édẹ́nì nípa “irú-ọmọ” kan tó ń bọ̀ wá dá aráyé nídè lọ́jọ́ kan? (Jẹ́n. 3:15; 12:7) Ó lè jẹ́ bẹ́ẹ̀. Bóyá ó lè ti bẹ̀rẹ̀ sí í yé e lọ́nà kan ṣá, pé òun náà wà lára àwọn tí Jèhófà fẹ́ lò láti mú ète rẹ̀ ṣẹ.

20. Báwo ni Ábúrámù ṣe fi hàn pé òun mọyì àǹfààní tí Jèhófà fún òun?

20 Ábúrámù mọyì àǹfààní tí Jèhófà fún un yìí gan-an ni. Bó ṣe ń rin ilẹ̀ náà wò káàkiri, ó ń dúró láti kọ́ pẹpẹ tó fi ń rúbọ sí Jèhófà. Ṣùgbọ́n ó dájú pé ṣe lá máa fẹ̀sọ̀ ṣe é torí àwọn ọmọ Kénáánì ṣì ń gbébẹ̀ nígbà yẹn. Ó kọ́kọ́ rúbọ nítòsí àwọn igi ńlá Mórè, ó sì tún rúbọ nítòsí Bẹ́tẹ́lì. Ó pe orúkọ Jèhófà, bóyá láti dúpẹ́ tọkàntọkàn lọ́wọ́ Ọlọ́run rẹ̀ bó ṣe ń ronú nípa bí ọjọ́ ọ̀la àwọn tó máa jẹ́ irú ọmọ rẹ̀ yòó ṣe rí. Ó sì ṣeé ṣe kó máa wàásù fún àwọn ọmọ Kénáánì tó wà ní àyíká rẹ̀. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 12:7, 8.) Àmọ́ ṣá, ọ̀pọ̀ nǹkan ṣì wà níwájú tí yóò dán ìgbàgbọ́ Ábúrámù wò gan-an bó ṣe ń bá ìrìn àjò ìgbésí ayé rẹ̀ lọ. Ábúrámù hùwà ọlọgbọ́n ṣá o, torí kò bojú wẹ̀yìn kó wá máa ronú nípa ibùgbé rẹ̀ àti gbogbo ìgbádùn tó fi sílẹ̀ ní Úrì. Ohun tó ń bẹ níwájú ló gbájú mọ́. Ìwé Hébérù 11:10 sọ nípa Ábúrámù pé: “Ó ń dúró de ìlú ńlá tí ó ní àwọn ìpìlẹ̀ tòótọ́, ìlú ńlá tí olùtẹ̀dó àti olùṣẹ̀dá rẹ̀ jẹ́ Ọlọ́run.”

21. Báwo ni ìmọ̀ wa nípa Ìjọba Ọlọ́run ṣe ju tí Ábúrámù lọ? Kí ló yẹ kó o rí i dájú pé o ṣe?

21 Ohun tí àwa tó ń sin Jèhófà lónìí mọ̀ nípa ìlú ìṣàpẹẹrẹ náà, ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run, pọ̀ gan-an ju èyí tí Ábúrámù mọ̀. A mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ní ọ̀run àti pé yóò pa ètò àwọn nǹkan búburú tó wà láyé run láìpẹ́. A tún mọ̀ pé Jésù Kristi tó jẹ́ Irú-ọmọ tí aráyé ti ń retí tipẹ́tipẹ́, ti ń ṣàkóso Ìjọba yẹn. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló máa jẹ́ fún wa láti wà níbẹ̀ nígbà tí Ábúráhámù bá jíǹde tó sì wá lóye ète Ọlọ́run ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́! Ǹjẹ́ o fẹ́ wà níbẹ̀ nígbà tí Jèhófà bá mu gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ pátápátá? Tó o bá fẹ́ wà níbẹ̀, ṣe ni kó rí i dájú pé ìwọ náà ń ṣe ohun tí Ábúrámù ṣe. Ṣe tán láti fi àwọn ohun kan du ara rẹ kó o lè ráyè ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run. Jẹ́ onígbọràn, kó o sì mọyì àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tí Jèhófà bá fún ọ gidigidi. Bí o ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Ábúrámù tó jẹ́ “baba gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́” yóò di baba tìrẹ náà, lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ!

^ ìpínrọ̀ 1 Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Ọlọ́run yí orúkọ Ábúrámù pa dà sí Ábúráhámù, tó túmọ̀ sí “Baba Ogunlọ́gọ̀.”—Jẹ́n. 17:5.

^ ìpínrọ̀ 4 Bákan náà, Ábúrámù ni Bíbélì máa ń kọ́kọ́ dárúkọ nínú àwọn ọmọ tí Térà bí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó kéré gan-an lọ́jọ́ orí sí ẹni tó jẹ́ àkọ́bí.

^ ìpínrọ̀ 6 Nígbà tó yá, Ọlọ́run yí orúkọ Sáráì pa dà sí Sárà, tó túmọ̀ sí “Ìyá Ọba.”—Jẹ́n. 17:15.

^ ìpínrọ̀ 12 Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé bóyá ni àwọn èèyàn ń fi ràkúnmí ṣe ẹran ọ̀sìn nígbà ayé Ábúrámù. Àmọ́, ìdí tí wọ́n fi sọ bẹ́ẹ̀ kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ rárá. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Bíbélì mẹ́nu kàn án pé Ábúrámù ní àwọn ràkúnmí.—Jẹ́n. 12:16; 24:35.