ORÍ KẸTÀDÍNLÓGÚN
“Wò Ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà!”
1, 2. (a) Báwo ni àjèjì kan ṣe kí Màríà? (b) Ìpinnu pàtàkì wo ni Màríà ní láti ṣe?
MÀRÍÀ gbójú sókè, ẹnu sì yà á gidigidi nígbà tí àlejò kan wọlé tọ̀ ọ́ wá. Àlejò náà kò béèrè bàbá tàbí ìyá rẹ̀. Màríà gan-an ló wá rí! Ó dá Màríà lójú pé kì í ṣe ará Násárétì. Kò sí bí àjèjì kan ṣe lè wọ inú ìlú kékeré tí Màríà ń gbé tí wọn ò ní mọ̀ pé àjèjì ni. Àmọ́ ní ti ọkùnrin yìí, kò síbi tó dé tí kò ti ní dá yàtọ̀. Ó tún wá kí Màríà lọ́nà tó ṣàjèjì sí i. Ó ní: “Kú déédéé ìwòyí o, ẹni tí a ṣe ojú rere sí lọ́nà gíga, Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ.”—Ka Lúùkù 1:26-28.
2 Báyìí ni Bíbélì ṣe bẹ̀rẹ̀ ìtàn Màríà, ọmọbìnrin Hélì tó jẹ́ ọmọ ìlú Násárétì tó wà ní Gálílì. Èyí sì jẹ́ ní àkókò tó ní láti ṣe ìpinnu pàtàkì kan ní ìgbésí ayé rẹ̀. Màríà ti ní àfẹ́sọ́nà. Jósẹ́fù ni orúkọ rẹ̀, iṣẹ́ káfíńtà ló sì ń ṣe. Jósẹ́fù kì í ṣe ọlọ́rọ̀, àmọ́ ó ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà. Torí náà, ó ṣeé ṣe kí Màríà ti ronú nípa bí ìgbésí ayé òun ṣe máa rí. Gẹ́gẹ́ bí ìyàwó ilé, á máa gbé ìgbésí ayé tó wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, á máa ran Jósẹ́fù lọ́wọ́, wọ́n á sì jọ tọ́ àwọn ọmọ tí wọ́n bá bí dàgbà. Àmọ́ láìròtẹ́lẹ̀, àlejò tó wọlé tọ̀ ọ́ wá yìí gbé iṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀ lé e lọ́wọ́. Iṣẹ́ yìí sì máa yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà.
3, 4. Tá a bá fẹ́ mọ irú ẹni tí Màríà jẹ́ gan-an, àwọn nǹkan wo ló yẹ ká mú kúrò lọ́kàn, kí ló sì yẹ ká fọkàn sí?
3 Ó máa ń ya ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́nu pé Bíbélì kò sọ ohun púpọ̀ fún wa nípa Màríà. Ohun díẹ̀ ló sọ nípa àwọn òbí rẹ̀, kò fi bẹ́ẹ̀ sọ nípa irú ẹni tó jẹ́, kò sì sọ ohunkóhun rárá nípa ìrísí rẹ̀. Síbẹ̀, ìwọ̀nba ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa Màríà fi irú ẹni tó jẹ́ hàn.
4 Tá a bá fẹ́ mọ irú ẹni tí Màríà jẹ́ gan-an, ó ṣe pàtàkì pé ká wò ré kọjá onírúurú ẹ̀kọ́ tí ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ti fi kọ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn nípa rẹ̀. Ká gbójú fo àìmọye ọ̀nà táwọn èèyàn ti gbà fi ọ̀dá yàwòrán rẹ̀, bí wọ́n ṣe fi òkúta mábílì gbẹ́ ẹ, tàbí bí wọ́n ṣe ń gbé e sójútáyé. Ẹ sì tún jẹ́ ká mọ́kàn kúrò lórí àwọn àlàyé àti ẹ̀kọ́ ìsìn tó ṣòroó lóye tó máa ń mú kí àwọn èèyàn pe obìnrin onírẹ̀lẹ̀ yìí ní àwọn orúkọ oyè kàǹkà-kàǹkà bí “Ìyá Ọlọ́run” àti “Ọbabìnrin Ọ̀run.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká fọkàn sí ohun tí Bíbélì sọ fún wa gan-an.
Èyí máa jẹ́ ká ní òye tí kò lẹ́gbẹ́ nípa irú ìgbàgbọ́ tó ní àti bá a ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.Áńgẹ́lì Kan Bẹ Màríà Wò
5. (a) Kí la lè rí kọ́ nípa Màríà látinú bí ìkíni Gébúrẹ́lì ṣe rí lọ́kàn rẹ̀? (b) Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la lè rí kọ́ lára Màríà?
5 Èèyàn lásán kọ́ ló bá Màríà lálejò o! Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì ni. Nígbà tó pe Màríà ní “ẹni tí a ṣe ojú rere sí lọ́nà gíga,” ọ̀rọ̀ náà “yọ” Màríà “lẹ́nu gidigidi,” ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kàyéfì nítorí ìkíni tó ṣàjèjì yìí. (Lúùkù 1:29) Ta ló ṣe ojú rere sí Màríà lọ́nà gíga? Màríà ò retí pé kí èèyàn kankan ṣe ojú rere sí òun lọ́nà gíga. Àmọ́, ojú rere tí Jèhófà Ọlọ́run ṣe sí Màríà ni áńgẹ́lì náà ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ìyẹn ṣe pàtàkì lójú Màríà. Síbẹ̀, kò jọra rẹ̀ lójú débi táá fi máa ronú pé òun ti rí ojú rere Ọlọ́run gbà ná. Àpẹẹrẹ tí Màríà fi lélẹ̀ yìí kọ́ wa pé ká sapá láti rí ojú rere Ọlọ́run, ká má sì jẹ́ kí ìgbéraga mú ká máa rò pé a ti rí i gbà ná. Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó nífẹ̀ẹ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀, ó sì máa ń tì wọ́n lẹ́yìn.—Ják. 4:6.
Màríà ò jọ ara rẹ̀ lójú débi táá fi máa rò pé òun ti rí ojú rere Ọlọ́run gbà ná
6. Àǹfààní wo ni áńgẹ́lì náà sọ fún Màríà pé ó máa ní?
6 Ó pọn dandan kí Màríà jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, torí pé àǹfààní tí kò rò tì ni áńgẹ́lì náà sọ pé ó máa jẹ́ tirẹ̀. Ó ṣàlàyé fún un pé ó máa bí ọmọ kan tó máa di ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú gbogbo aráyé. Gébúrẹ́lì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀ fún un, yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lórí ilé Jékọ́bù títí láé, kì yóò sì sí òpin fún ìjọba rẹ̀.” (Lúùkù 1:32, 33) Ó dájú pé Màríà mọ ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún Dáfídì ní èyí tó ju ẹgbẹ̀rún ọdún kan ṣáájú ìgbà yẹn pé ọ̀kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ máa ṣàkóso títí láé. (2 Sám. 7:12, 13) Èyí fi hàn pé ọmọ rẹ̀ ló máa di Mèsáyà tí àwọn èèyàn Ọlọ́run ti ń retí láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn!
7. (a) Kí ni ìbéèrè tí Màríà bi áńgẹ́lì náà jẹ́ ká mọ̀ nípa Màríà? (b) Kí làwọn ọ̀dọ́ òde òní lè rí kọ́ lára Màríà?
7 Pabanbarì rẹ̀ ni pé áńgẹ́lì náà sọ fún Màríà pé a ó sì máa pé ọmọ rẹ̀ yìí ní “Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ.” Báwo ni obìnrin tó jẹ́ èèyàn ṣe máa bí Ọmọ Ọlọ́run? Báwo ni Màríà tiẹ̀ ṣe fẹ́ bímọ? Òun àti Jósẹ́fù ti ń fẹ́ra sọ́nà lóòótọ́, àmọ́ wọn kò tíì ṣègbéyàwó. Ohun tí Màríà béèrè láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ nìyẹn. Ó ní: “Báwo ni èyí yóò ṣe rí bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bí èmi kò ti ń ní ìbádàpọ̀ kankan pẹ̀lú ọkùnrin?” (Lúùkù 1:34) Kíyè sí i pé kò ti Màríà lójú rárá láti sọ pé òun kò tíì ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin rí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó mọyì ipò wúńdíá rẹ̀. Lóde ìwòyí, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tètè máa ń wá ẹni bá wọn lò pọ̀, ó sì máa ń yá wọn lára láti fi àwọn tí kò bá tíì ní ìbálòpọ̀ ṣe yẹ̀yẹ́. Ayé ti yàtọ̀ sí tàtijọ́ lóòótọ́, àmọ́ Jèhófà ò tíì yí pa dà. (Mál. 3:6) Bí Jèhófà ṣe mọyì àwọn tó ń fi ìlànà rẹ̀ sílò nígbà ayé Màríà náà ló ṣe mọyì wọn lóde òní pẹ̀lú.—Ka Hébérù 13:4.
8. Báwo ni Màríà tó jẹ́ aláìpé ṣe lè bí ọmọ tí kò ní àbààwọ́n ẹ̀ṣẹ̀?
8 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni Màríà, tó sì tún jẹ́ adúróṣinṣin, aláìpé ló ṣì jẹ́. Báwo ló ṣe máa wá bí Ọmọ Ọlọ́run tó máa jẹ́ ẹni pípé? Gébúrẹ́lì ṣàlàyé pé: “Ẹ̀mí mímọ́ yóò bà lé ọ, agbára Ẹni Gíga Jù Lọ yóò sì ṣíji bò ọ́. Nítorí ìdí èyí pẹ̀lú, ohun tí a bí ni a ó pè ní mímọ́, Ọmọ Ọlọ́run.” (Lúùkù 1:35) Ńṣe ni ọmọ máa ń jogún àìpé àti ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ òbí. Ṣùgbọ́n, Jèhófà máa ṣe iṣẹ́ ìyanu àrà ọ̀tọ̀ nínú ọ̀ràn ti Màríà. Ó máa fi ìwàláàyè Ọmọ rẹ̀ sínú ilé ọlẹ̀ Màríà láti ọ̀run, yóò sì wá fi ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀, ìyẹn ẹ̀mí mímọ́, ‘ṣíji bo’ Màríà. Èyí ni kò ní jẹ́ kí ọmọ náà ní àbààwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ kankan. Ǹjẹ́ Màríà gba ìlérí áńgẹ́lì yìí gbọ́? Èsì wo ni Màríà fún un?
Èsì Tí Màríà Fún Gébúrẹ́lì
9. (a) Kí nìdí tí kò fi tọ̀nà pé kí àwọn kan máa ṣiyè méjì nípa ìtàn Màríà? (b) Báwo ni Gébúrẹ́lì ṣe fún ìgbàgbọ́ Màríà lókun?
9 Ó ṣòro fún àwọn tó ń ṣiyè méjì nípa ẹ̀kọ́ Bíbélì, títí kan àwọn kan tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ìsìn nínú ṣọ́ọ̀ṣì, láti gbà pé wúńdíá lè bímọ. Pẹ̀lú adúrú ìwé tí wọ́n kà, òótọ́ ọ̀rọ̀ tó ṣe kedere yìí ò yé wọn. Gébúrẹ́lì sọ pé: “Lọ́dọ̀ Ọlọ́run kò sí ìpolongo kankan tí yóò jẹ́ aláìṣeéṣe.” (Lúùkù 1:37) Màríà gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Gébúrẹ́lì sọ, torí pé ó jẹ́ ọmọbìnrin kan tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára. Àmọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé Màríà ní ìgbàgbọ́, kì í ṣe òmùgọ̀ o. Ó nílò ẹ̀rí tó máa gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀ kà, ohun tá a sì retí pé kí ẹni tó ní làákàyè ṣe nìyẹn. Gébúrẹ́lì sì ti wá ṣe tán láti fún un ní ẹ̀rí síwájú sí i. Ó sọ fún un nípa Èlísábẹ́tì, ìbátan rẹ̀ àgbà tó ti pẹ́ táwọn èèyàn ti mọ̀ sí àgàn pé Ọlọ́run ti jẹ́ kó lóyún lọ́nà ìyanu!
10. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká rò pé àǹfààní tí Màríà ní yìí kò kó àníyàn tàbí ìnira bá a?
10 Kí ni Màríà máa wá ṣe báyìí? Iṣẹ́ ti délẹ̀ fún un, ẹ̀rí tó dájú sì wà pé Ọlọ́run máa ṣe gbogbo ohun tí Gébúrẹ́lì sọ. Kò wá yẹ ká rò pé àǹfààní tí Màríà ní yìí ò kó àníyàn tàbí ìnira kankan bá a o! Ohun kan ni pé ó gbọ́dọ̀ ro ti àdéhùn tó wà láàárín òun àti Jósẹ́fù. Ṣé Jósẹ́fù ṣì máa fẹ́ ẹ sílé tó bá gbọ́ pé ó ti lóyún? Ohun mìíràn ni pé ó ṣeé ṣe kí iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́ yìí kà á láyà. Oyún ẹni tó ṣeyebíye jù lọ nínú gbogbo ìṣẹ̀dá Ọlọ́run, ìyẹn ọmọ tó jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún Ọlọ́run, ló máa wà níkùn rẹ̀. Ó ní láti bójú tó o nígbà tó wà ní ìkókó tó nílò ìtọ́jú lójú méjèèjì, kó sì
dáàbò bò ó nínú ayé búburú ìgbà yẹn. Ká sòótọ́, iṣẹ́ kékeré kọ́ ló já lé Màríà léjìká!11, 12. (a) Kí ni àwọn ọkùnrin onígboyà àti adúróṣinṣin pàápàá máa ń ṣe nígbà míì tí Ọlọ́run bá fún wọn ní iṣẹ́ tí kò rọrùn? (b) Kí ni ìdáhùn tí Màríà fún Gébúrẹ́lì fi hàn nípa irú ẹni tó jẹ́?
11 Bíbélì fi hàn pé láwọn ìgbà míì, àwọn ọkùnrin onígboyà àti adúróṣinṣin pàápàá máa ń lọ́ tìkọ̀ láti tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ tí kò rọrùn lọ́wọ́ Ọlọ́run. Mósè ṣàròyé pé ọ̀rọ̀ ò já geere lẹ́nu òun débi tí òun á fi lè ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí agbọ̀rọ̀sọ fún Ọlọ́run. (Ẹ́kís. 4:10) Jeremáyà ní tiẹ̀ sọ pé “ọmọdé lásán” ni òun, pé òun ti kéré jù fún iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé òun lọ́wọ́. (Jer. 1:6) Ńṣe ni Jónà tiẹ̀ sá lọ kúrò nídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an! (Jónà 1:3) Kí ni Màríà ṣe ní tiẹ̀?
12 Kódà títí di òní, ọ̀pọ̀ àwọn tó ní ìgbàgbọ́ ló mọ̀ nípa ìdáhùn rẹ̀ tó fi hàn pé ó níwà ìrẹ̀lẹ̀ àti pé ó fẹ́ láti ṣègbọràn. Ó sọ fún Gébúrẹ́lì pé: “Wò ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà! Kí ó ṣẹlẹ̀ sí mi ní ìbámu pẹ̀lú ìpolongo rẹ.” (Lúùkù 1:38) Ipò ẹrúbìnrin ló rẹlẹ̀ jù lọ láàárín àwọn ìránṣẹ́ inú ilé, ọ̀gá rẹ̀ ló sì máa ń pinnu bó ṣe máa lo ìgbésí ayé rẹ̀. Màríà náà gbà pé Jèhófà tó jẹ́ Ọ̀gá òun ló yẹ kó máa darí ìgbésí ayé òun. Ó mọ̀ pé mìmì kan ò lè mi òun lọ́dọ̀ Jèhófà, torí pé kì í fi àwọn tó bá jẹ́ adúróṣinṣin sílẹ̀. Ó tún dá a lójú pé Jèhófà máa ràn án lọ́wọ́ tó bá ṣe gbogbo nǹkan tó lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ tó gba ìsapá yìí.—Sm. 18:25.
Màríà mọ̀ pé mìmì kan ò lè mi òun lọ́dọ̀ Jèhófà, torí pé Ọlọ́run adúróṣinṣin ni
13. Tó bá jọ pé iṣẹ́ tí Ọlọ́run fún wa ṣòro tàbí tó tiẹ̀ dà bí èyí tá ò lè ṣe, kí ni Màríà ṣe tó lè ran àwa náà lọ́wọ́?
13 Nígbà míì Ọlọ́run lè ní ká ṣe ohun tó dà bíi pé ó ṣòro, tàbí ohun tá a tiẹ̀ kà sí èyí tá ò lè ṣe pàápàá. Àmọ́, nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sọ ọ̀pọ̀ nǹkan fún wa tó lè mú ká gbẹ́kẹ̀ lé e, ká sì fi ọkàn tán an pátápátá, bíi ti Màríà. (Òwe 3:5, 6) Ṣé a máà ṣe bẹ́ẹ̀? Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run máa san wá lẹ́san rere, ìyẹn á sì jẹ́ ká rí ìdí tí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú rẹ̀ fi gbọ́dọ̀ lágbára sí i.
Màríà Lọ Kí Èlísábẹ́tì
14, 15. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe mú kí Màríà jàǹfààní látinú ìbẹ̀wò tó ṣe sọ́dọ̀ Èlísábẹ́tì àti Sekaráyà? (b) Kí ni ọ̀rọ̀ tí Màríà sọ nínú Lúùkù 1:46-55 jẹ́ ká mọ̀ nípa rẹ̀?
14 Ọwọ́ pàtàkì ni Màríà fi mú ọ̀rọ̀ tí Gébúrẹ́lì sọ fún un nípa Èlísábẹ́tì. Ó mọ̀ pé Èlísábẹ́tì máa lóye òun dáadáa torí pé àwọn méjèèjì ni nǹkan ìyanu ṣẹlẹ̀ sí. Kíá ni Màríà gbéra, tó sì rin ìrìn àjò tó lè gba nǹkan bí ọjọ́ mẹ́ta tàbí mẹ́rin lọ sí ẹkùn ilẹ̀ olókè Lúùkù 1:39-45) Láìsí tàbí ṣùgbọ́n, gbogbo ìlérí tí Jèhófà ti ṣe fún Màríà ló máa ní ìmúṣẹ.
ńláńlá ti Júdà. Bó ṣe ń wọnú ilé Èlísábẹ́tì àti Sekaráyà àlùfáà, Jèhófà fún un ní ẹ̀rí míì tí kò ṣeé já ní koro kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lè lágbára sí i. Èlísábẹ́tì kíyè sí i pé bí òun ṣe gbọ́ ìkíni Màríà ni ọmọ inú ilé ọlẹ̀ òun fò fáyọ̀. Èlísábẹ́tì wá kún fún ẹ̀mí mímọ́, ó sì pe Màríà ní “ìyá Olúwa mi.” Ọlọ́run ti fi han Èlísábẹ́tì pé ọmọ tí Màríà máa bí, ìyẹn Mèsáyà, á di Olúwa rẹ̀. Ọlọ́run tún mí sí i láti yin Màríà nítorí pé ó ṣègbọràn láìyẹsẹ̀, ó ní: “Aláyọ̀ pẹ̀lú ni obìnrin náà tí ó gbà gbọ́.” (15 Màríà náà wá sọ̀rọ̀, Ọlọ́run sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wà nínú Bíbélì. (Ka Lúùkù 1:46-55.) Èyí ló gùn jù nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí Màríà sọ nínú Bíbélì, ó sì jẹ́ ká mọ púpọ̀ nípa irú ẹni tó jẹ́. Ó fi hàn pé Màríà moore, ó sì ní ẹ̀mí ìmọrírì. Èyí hàn nínú bó ṣe ń yin Jèhófà pé ó fún òun ní àǹfààní láti di ìyá Mèsáyà. Ó fi bí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó hàn nígbà tó ń sọ bí Jèhófà ṣe ń rẹ àwọn agbéraga àti alágbára sílẹ̀ tó sì ń ran àwọn ẹni rírẹlẹ̀ àti tálákà tó ń fẹ́ láti sìn ín lọ́wọ́. Ó tún fi bí ìmọ̀ rẹ̀ ṣe pọ̀ tó hàn. Àwọn kan díwọ̀n rẹ̀ pé ó lé ní ìgbà ogún tó fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù! *
16, 17. (a) Báwo ni Màríà àti ọmọ rẹ̀ ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nípa irú ẹ̀mí tó yẹ ká ní? (b) Àǹfààní wo ni ìbẹ̀wò Màríà sọ́dọ̀ Èlísábẹ́tì rán wa létí rẹ̀?
16 Ó ṣe kedere pé Màríà máa ń ṣàṣàrò lé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lórí gan-an. Síbẹ̀, ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó gbé ohun tó sọ karí Ìwé Mímọ́ dípò kó máa sọ èrò ti ara rẹ̀. Ọjọ́ kan ń bọ̀ tí ọmọ tó lóyún rẹ̀ sínú náà máa fi irú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ hàn. Ó máa sọ fáwọn èèyàn pé: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.” (Jòh. 7:16) Ó yẹ kí àwa náà bi ara wa pé: ‘Ǹjẹ́ èmi náà ní irú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Àbí èrò ti ara mi ni mo fi ń kọ́ àwọn èèyàn?’ Ohun tó tọ́ ni Màríà ṣe ní tirẹ̀.
17 Màríà lo nǹkan bí oṣù mẹ́ta lọ́dọ̀ Èlísábẹ́tì, àwọn méjèèjì sì fún ara wọn ní ìṣírí lọ́pọ̀lọpọ̀. (Lúùkù 1:56) Bí Bíbélì ṣe sọ̀rọ̀ nípa ìbẹ̀wò yìí lọ́nà tó fani mọ́ra rán wa létí àǹfààní tá a lè rí lára àwọn ọ̀rẹ́ wa. Tá a bá yan ọ̀rẹ́ lára àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run wa tọkàntọkàn, ó dájú pé a máa ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run, a ó sì túbọ̀ sún mọ́ ọn. (Òwe 13:20) Àmọ́, nígbà tó ṣe, àkókò tó fún Màríà láti pa dà sílé. Kí ni Jósẹ́fù máa sọ tó bá mọ̀ pé Màríà ti lóyún?
Màríà àti Jósẹ́fù
18. Kí ni Màríà sọ fún Jósẹ́fù? Kí ni Jósẹ́fù pinnu láti ṣe?
18 Kò jọ pé Màríà dúró di ìgbà tí oyún rẹ̀ yọ kó tó sọ fún Jósẹ́fù. Ṣùgbọ́n kó tó sọ fún un, ó lè ti máa ronú nípa ohun tí ọkùnrin tó ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, tó sì jẹ́ ọmọlúwàbí yìí máa ṣe lẹ́yìn tó bá gbọ́. Síbẹ̀ náà, ó lọ bá Jósẹ́fù ó sì sọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ fún un. Bí a ṣe lè retí, ọ̀rọ̀ náà kó ìdààmú bá Jósẹ́fù gan-an. Ó wù ú pé kó gba ọ̀rọ̀ Màríà olólùfẹ́ rẹ̀ gbọ́, àmọ́ ó dà bíi pé Màríà ti hùwà ọ̀dàlẹ̀. Bíbélì ò sọ ohun tó wá sí Jósẹ́fù lọ́kàn tàbí ohun tó rò lórí ọ̀rọ̀ yìí fún wa. Àmọ́ Bíbélì sọ pé ó pinnu láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, torí pé ńṣe ni wọ́n máa ń wo àwọn tó bá ń fẹ́ ara wọn sọ́nà láyé ìgbà yẹn bíi pé wọ́n ti ṣègbéyàwó. Síbẹ̀, Jósẹ́fù kò fẹ́ dójú tì í ní Mát. 1:18, 19) Ó ti ní láti dun Màríà gan-an pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí kó ìdààmú bá Jósẹ́fù. Síbẹ̀, Màríà kò dá Jósẹ́fù lẹ́bi pé kò fẹ́ gba òun gbọ́.
gbangba, kò sì fẹ́ kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ rẹ̀ láìdáa. Torí náà, ó pinnu láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní bòókẹ́lẹ́. (19. Báwo ni Jèhófà ṣe ran Jósẹ́fù lọ́wọ́ kó lè ṣe ohun tó tọ́?
19 Jèhófà ran Jósẹ́fù lọ́wọ́ kó lè ṣe ohun tó tọ́ nípa ọ̀rọ̀ náà. Áńgẹ́lì Ọlọ́run sọ fún Jósẹ́fù lójú àlá pé ọ̀nà ìyanu ni Màríà gbà lóyún lóòótọ́. Ìyẹn ti ní láti fi Jósẹ́fù lọ́kàn balẹ̀! Òun náà wá ṣe bíi ti Màríà, ìyẹn ni pé ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ kó ṣe. Ó fẹ́ Màríà sílé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀ láti tọ́ Ọmọ Jèhófà, èyí tó jẹ́ ojúṣe àrà ọ̀tọ̀.—Mát. 1:20-24.
20, 21. Kí ni àwọn tọkọtaya àtàwọn tó ń gbèrò láti ṣègbéyàwó lè rí kọ́ lára Màríà àti Jósẹ́fù?
20 Ó yẹ kí àwọn tọkọtaya àtàwọn tó ń gbèrò láti ṣègbéyàwó kẹ́kọ̀ọ́ lára tọkọtaya tó gbé ayé ní ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn yìí. Ó dájú pé bí Jósẹ́fù ṣe ń rí i tí ìyàwó rẹ̀ ń ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí abiyamọ ni inú rẹ̀ ń dùn pé áńgẹ́lì Jèhófà tọ́ òun sọ́nà. Jósẹ́fù ti ní láti rí ìdí tó fi yẹ kéèyàn máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà tó bá ń ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì. (Sm. 37:5; Òwe 18:13) Kò sí iyè méjì pé tí Jósẹ́fù bá ń ṣe àwọn ìpinnu gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé, ó máa ń fara balẹ̀, ó sì máa ń gba ti ìdílé rẹ̀ rò.
21 Ṣùgbọ́n kókó wo la rí dì mú nínú bí Màríà ṣe múra tán láti fẹ́ Jósẹ́fù? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó kọ́kọ́ ṣòro fún Jósẹ́fù láti gba Màríà gbọ́, síbẹ̀ Màríà ní sùúrù títí tí Jósẹ́fù fi pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe, torí pé òun ló ń bọ̀ wá di olórí ìdílé. Èyí ràn án lọ́wọ́ lẹ́yìn tí wọ́n ṣègbéyàwó, ẹ̀kọ́ nìyẹn sì jẹ́ fún àwọn obìnrin Kristẹni lóde òní. Lákòótán, ó ṣeé ṣe kí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ti jẹ́ kí Jósẹ́fù àti Màríà rí àǹfààní tó wà nínú kí tọkọtaya máa fi inú han ara wọn.—Ka Òwe 15:22.
22. Kí ni Jósẹ́fù àti Màríà fi pilẹ̀ ìgbéyàwó wọn? Kí ni wọ́n ń fojú sọ́nà fún?
22 Ohun tó dára jù lọ ni tọkọtaya yìí fi pilẹ̀ ìgbéyàwó wọn. Ìfẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run ló gbawájú jù lọ lọ́kàn àwọn méjèèjì, wọ́n sì fẹ́ láti mú inú Ọlọ́run dùn gẹ́gẹ́ bí òbí tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́, tó sì mọyì ọmọ. Dájúdájú wọ́n máa rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà, àmọ́ iṣẹ́ kékeré kọ́ ló wà níwájú wọn. Wọ́n ń fojú sọ́nà láti tọ́ Jésù dàgbà, ẹni tó máa di ọkùnrin títóbilọ́lá jù lọ tó tíì gbé ayé rí.
^ ìpínrọ̀ 15 Ó dájú pé lára àwọn ọ̀rọ̀ tí Màríà fà yọ ni èyí tí obìnrin adúróṣinṣin náà, Hánà, sọ torí pé òun náà rí ìbùkún Jèhófà gbà ní ti pé Ọlọ́run fún un lọ́mọ.—Wo àpótí náà, “Àdúrà Àrà Ọ̀tọ̀ Méjì,” ní Orí 6.