Àwòrán Tí Wọ́n Gbẹ́ Sára Ògiri ní Íjíbítì Àtijọ́ Ti Ohun Tí Bíbélì Sọ Lẹ́yìn
Àwòrán kan tó ga tó mítà mẹ́jọ, tí wọ́n gbẹ́ sára ògiri wà nítòsí ibi àbáwọlé tẹ́ńpìlì òòṣà Ámúnì nílùú Kánákì ní Íjíbítì àtijọ́. Àwọn òjọ̀gbọ́n sọ pé ṣe ni àwòrán náà ń ṣàlàyé bí Fáráò Ṣíṣákì ṣe ṣẹ́gun àwọn ilẹ̀ tó wà ní àríwá ìlà oòrùn Íjíbítì, títí kan Júdà àti ìjọba àríwá Ísírẹ́lì.
Àwòrán náà fi Ámúnì hàn, bó ṣe ń fa àwọn tó mú ní òǹdè, tó ju àádọ́jọ (150) lọ lé Ṣíṣákì tàbí Ṣéṣóńkì lọ́wọ́. a Ìlú kọ̀ọ̀kan tó ṣẹ́gun ló ti mú òǹdè kọ̀ọ̀kan. Wọ́n kọ orúkọ ìlú táwọn òǹdè náà ti wá sára ìkọ̀ọ̀kan wọn. Àwọn orúkọ ìlú kan wà nínú àwòrán náà tó ṣì ṣeé kà, àwọn orúkọ ìlú míì sì wà níbẹ̀ táwọn tó ń ka Bíbélì mọ̀ dáadáa. Lára àwọn ìlú náà ni Bẹti-ṣéánì, Gíbéónì, Mẹ́gídò àti Ṣúnémù.
Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa bí Íjíbítì ṣe ṣígun wọ Júdà. (1 Àwọn Ọba 14:25, 26) Kódà, Bíbélì sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí Ṣíṣákì ṣe ṣígun dé. Ó ní: “Ní ọdún karùn-ún Ọba Rèhóbóámù, Ṣíṣákì ọba Íjíbítì wá gbéjà ko Jerúsálẹ́mù. . . . Ó ní ẹgbẹ̀rún kan ó lé igba (1,200) kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ọ̀kẹ́ mẹ́ta (60,000) àwọn agẹṣin pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun tí kò níye, tí wọ́n bá a wá láti Íjíbítì . . . Ó gba àwọn ìlú olódi tó wà ní Júdà, níkẹyìn, ó dé Jerúsálẹ́mù.”—2 Kíróníkà 12:2-4.
Àwòrán tí wọ́n gbẹ́ sára ògiri nílùú Kánákì nìkan kọ́ ni ẹ̀rí táwọn awalẹ̀pìtàn rí pé òótọ́ ni Ṣíṣákì gbógun wọ ilẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àfọ́kù òkúta kan wà tí wọ́n rí nílùú Mẹ́gídò tí Bíbélì sọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì kọ “Ṣéṣóńkì” sára òkúta náà.
Àkọsílẹ̀ tó péye tá a rí nínú Bíbélì nípa bí Ṣíṣákì ṣe ṣẹ́gun Júdà jẹ́ ká rí bí àwọn tó kọ Bíbélì ṣe jẹ́ olóòótọ́ tó. Wọ́n fi òótọ́ inú ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìgbà tí orílẹ̀-èdè wọn ṣẹ́gun ọ̀tá àti ìgbà táwọn ọ̀tá rẹ́yìn orílẹ̀-èdè tiwọn náà. Irú ìṣòtítọ́ yìí ò wọ́pọ̀ láàárín àwọn míì tí wọ́n jẹ́ òǹkọ̀wé nígbà àtijọ́.
a Bí Bíbélì ṣe kọ “Ṣíṣákì” jẹ́ ká rí báwọn Hébérù ṣe máa ń pe orúkọ náà.