Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Bíbélì Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Láti Jáwọ́ Nínú Lílo Oògùn Nílòkulò?

Ṣé Bíbélì Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Láti Jáwọ́ Nínú Lílo Oògùn Nílòkulò?

 Ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ló ń kú lọ́dọọdún torí pé wọ́n ń lo oògùn olóró tàbí torí pé wọ́n ti sọ oògùn di bárakú. Iye àwọn tó ń lo oògùn nílòkulò túbọ̀ pọ̀ sí i lásìkò àrùn Kòrónà. Àmọ́, ìmọ̀ràn Bíbélì ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú lílo oògùn nílòkulò. Ìmọ̀ràn Bíbélì sì lè ran ìwọ náà lọ́wọ́ tó o bá nírú ìṣòro yìí. a

Nínú àpilẹ̀kọ yìí

 Kí nìdí tó fi yẹ kó o jẹ́ kí Bíbélì ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú lílo oògùn tó ti di bárakú fún ẹ?

 Ìwádìí fi hàn pé ìdánìkanwà, ìdààmú ọkàn, àníyàn tàbí ìrẹ̀wẹ̀sì wà lára àwọn ohun tó ń mú káwọn kan máa lo oògùn nílòkulò. Ìmọ̀ràn Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro tó lè mú kéèyàn ro ara pin débi táá fi bẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn nílòkulò. Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé a lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. (Sáàmù 25:14) Ó sì dájú pé Jèhófà lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro tó kọjá agbára rẹ.​—Máàkù 11:22-24.

 Àwọn ohun mẹ́rin tí Bíbélì sọ pé o lè ṣe tó o bá fẹ́ jáwọ́ nínú lílo oògùn tó ti di bárakú fún ẹ

  1.  1. Sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run. b (Jòhánù 17:3) Òun ni Ẹlẹ́dàá wa, òun sì ni alágbára gbogbo. Síbẹ̀, Baba wa ọ̀run yìí nífẹ̀ẹ́ rẹ dénú, ó sì fẹ́ kó o sún mọ́ òun kó lè fi agbára ńlá rẹ̀ ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Àìsáyà 40:29-31; Jémíìsì 4:8) Ó ṣèlérí pé tó o bá ṣe ìfẹ́ òun, nǹkan máa dáa fún ẹ lọ́jọ́ iwájú.​—Jeremáyà 29:11; Jòhánù 3:16.

  2.  2. Ní kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́. Gbàdúrà sí Ọlọ́run, pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí ìṣòro oògùn tó ti di bárakú fún ẹ, kó o lè ‘jẹ́ mímọ́, kó o sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.’ (Róòmù 12:1) Ó máa lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti fún ẹ ní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá.” (2 Kọ́ríńtì 4:7; Lúùkù 11:13) Agbára yìí máa jẹ́ kó o jáwọ́ nínú lílo oògùn nílòkulò, kó o sì ní “ìwà tuntun” èyí tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu.​—Kólósè 3:9, 10.

  3.  3. Jẹ́ kí èrò rẹ bá ti Ọlọ́run mu. (Àìsáyà 55:9) Ó máa jẹ́ kó o “di tuntun nínú agbára tó ń darí ìrònú” rẹ, tàbí lédè míì kó o yí ọ̀nà tó o gbà ń ronú pa dà. (Éfésù 4:23) Inú Bíbélì ni èrò Ọlọ́run wà, torí náà ó dáa kó o máa ka Bíbélì nígbà gbogbo. (Sáàmù 1:1-3) Ọ̀pọ̀ èèyàn ti jàǹfààní nínú bí wọ́n ṣe jẹ́ káwọn míì kọ́ wọn lóhun tó wà nínú Bíbélì. (Ìṣe 8:30, 31) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, o lè wá sí àwọn ìpàdé tá a máa ń ṣe torí pé ibẹ̀ la ti máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tá a sì máa ń rí bá a ṣe lè fàwọn ohun tá à ń kọ́ sílò láyé wa.

  4.  4. Yan àwọn ọ̀rẹ́ gidi. Àwọn ọ̀rẹ́ tó ò ń bá rìn ló máa pinnu bó ṣe máa rọrùn fún ẹ tó láti jáwọ́ nínú lílo oògùn nílòkulò. (Òwe 13:20) Àwọn ọ̀rẹ́ gidi wà láàárín àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run, àwọn sì ni Ọlọ́run fẹ́ kó o máa bá rìn. (Sáàmù 119:63; Róòmù 1:12) Kò tán síbẹ̀ o, fọgbọ́n yan eré ìnàjú tó ò ń wò torí pé kì í pẹ́ tá a fi máa ń hùwà bíi táwọn tá à ń wò, tá à ń tẹ́tí sí tàbí tá à ń kà nípa wọn. Yẹra fún ohunkóhun tó lè mú kó nira fún ẹ láti jáwọ́ nínú ìwà burúkú yìí.​—Sáàmù 101:3; Émọ́sì 5:14.

 Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí ìṣòro yìí

 Sáàmù 27:10: “Kódà, tí bàbá mi àti ìyá mi bá kọ̀ mí sílẹ̀, Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.”

 “Mi ò mọ bàbá tó bí mi, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kó ṣe mí bíi pé mi ò rẹ́ni fojú jọ. Nígbà tí mo wá mọ̀ pé ẹni gidi ni Jèhófà àti pé ó nífẹ̀ẹ́ mi, èyí mú káyé mi nítumọ̀, mo sì jáwọ́ nínú lílo oògùn nílòkulò.”​—Wilby, láti Haiti.

 Sáàmù 50:15: “Pè mí ní àkókò wàhálà. Màá gbà ọ́ sílẹ̀.”

 “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ẹsẹ Bíbélì yìí ràn mí lọ́wọ́, kódà láwọn ìgbà tó bá ń ṣe mí bíi kí n tún lo oògùn nílòkulò. Jèhófà ràn mí lọ́wọ́.”​—Serhiy, láti Ukraine.

 Òwe 3:56: “Fi gbogbo ọkàn rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà,má sì gbára lé òye tìrẹ. Máa kíyè sí i ní gbogbo ọ̀nà rẹ, á sì mú kí àwọn ọ̀nà rẹ tọ́.”

 “Ẹsẹ Bíbélì yìí ràn mí lọ́wọ́ kí n lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà dípò ara mi. Jèhófà sì fún mi lókun tí mo nílò láti yí ayé mi pa dà pátápátá.”​—Michele, láti Ítálì.

 Àìsáyà 41:10: “Má bẹ̀rù, torí mo wà pẹ̀lú rẹ. Má ṣàníyàn, torí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Màá fún ọ lókun, àní, màá ràn ọ́ lọ́wọ́, ní tòótọ́, màá fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin.”

 “Ara mi kì í balẹ̀ rárá nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í jáwọ́ nínú lílo oògùn nílòkulò. Ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ kó dá mi lójú pé Jèhófà máa ràn mí lọ́wọ́ kí ara mi lè balẹ̀, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.”​—Andy, láti South Africa.

 1 Kọ́ríńtì 15:33, àlàyé ìsàlẹ̀: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ. Ẹgbẹ́ búburú ń ba ìwà ọmọlúwàbí jẹ́.”

 “Àwọn tí mò ń bá rìn ló kọ́ mi bí wọ́n ṣe ń lo oògùn nílòkulò. Ohun tó ràn mí lọ́wọ́ láti jáwọ́ ni pé mi ò báwọn ṣọ̀rẹ́ mọ́, mo sì wá àwọn ọ̀rẹ́ tuntun tí ìwà wọn tẹ́ mi lọ́rùn.”​—Isaac, láti Kẹ́ńyà.

 2 Kọ́ríńtì 7:1: “Ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ara àti ti ẹ̀mí.”

 “Àwọn ọ̀rọ̀ yẹn ràn mí lọ́wọ́ kí n lè sapá láti wẹ ara mi mọ́, kí n sì jáwọ́ nínú àwọn ohun tó lè ṣe mí léṣe, irú bíi lílo oògùn nílòkulò.”​—Rosa, láti Kòlóńbíà.

 Fílípì 4:13: “Mo ní okun láti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ẹni tó ń fún mi lágbára.”

 “Mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ràn mí lọ́wọ́, torí mo mọ̀ pé agbára mi ò gbé e láti jáwọ́ nínú lílo oògùn nílòkulò. Jèhófà sí fún mi lókun tí mo nílò láti jáwọ́.”​—Patrizia, láti Ítálì.

 Bí ìmọ̀ràn Bíbélì ṣe ran àwọn kan lọ́wọ́ láti borí ìṣòro oògùn tó ti di bárakú fún wọn

 Àdúgbò tí ìwà ipá pọ̀ sí ni wọ́n ti tọ́ Joseph Ehrenbogen dàgbà, èyí ló mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í mu ọtí lámujù, ó sì ń lo oògùn nílòkulò. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú nítorí pé ó loògùn nílòkulò. Ẹsẹ Bíbélì kan ló jẹ́ kó dá a lójú pé ó lè yí pa dà. Ka ìtàn ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ náà “Mo Kọ́ Láti Bọ̀wọ̀ fún Àwọn Obìnrin Kí N Sì Mọyì Ara Mi.”

 Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Dmitry Korshunov sapá kó lè jáwọ́ nínú ọtí àmujù. Wo fídíò náà ‘Ọ̀rọ̀ Ara Mi Sú Mi’ kó o lè mọ ohun tó ràn án lọ́wọ́ láti jáwọ́.

 Ṣé Bíbélì ta ko gbígba ìtọ́jú ìṣègùn láti borí ìṣòro oògùn tó ti di bárakú?

 Rárá. Bíbélì sọ pé: “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn, àmọ́ àwọn tó ń ṣàìsàn nílò rẹ̀.” (Mátíù 9:12) Bákan náà , Àjọ Tó Ń Rí sí Lílo Oògùn Olóró Lorílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Àrùn tó le gan-an ni lílo oògùn olóró tàbí lílo oògùn nílòkulò jẹ́, ó sì máa ń ṣòro gan-an láti jáwọ́ nínú àṣà yìí, láìka bó ti wu ẹni náà tó láti jáwọ́.” Ó dájú pé agbára Jèhófà lè ran ẹnikẹ́ni lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú àṣà yìí. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tí ìmọ̀ràn Bíbélì ti ràn lọ́wọ́ láti borí àṣà yìí ṣì nílò ìtọ́jú ìṣègùn kí wọ́n lè jáwọ́ pátápátá nínú àṣà náà. c Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan tó ń jé Allen sọ pé: “Nígbà tí mo fẹ́ jáwọ́ nínú ọtí mímu, gbogbo ara ló bẹ̀rẹ̀ sí í ro mí. Ìgbà yẹn ni mo tó gbà pé lẹ́yìn ìmọ̀ràn Bíbélì tí mo ti fi sílò, mo tún nílò ìtọ́jú ìṣègùn náà.”

 Ṣé Bíbélì ta ko kéèyàn lo oògùn fún ìlera?

 Rárá. Kódà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé èèyàn lè lo ọtí láti tọ́jú egbò tàbí láti jẹ́ kí ìrora ẹni tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú dín kù. (Òwe 31:6; 1 Tímótì 5:23) Síbẹ̀, bí ọtí ni àwọn oògùn tó máa ń dín ìrora kù jẹ́, wọ́n lè di bárakú. Torí náà, ó dáa kéèyàn mọ bó ṣe máa lo àwọn oògùn tó ń dín ìrora kù, kó má bàa sọ ọ́ di bárakú.​—Òwe 22:3.

a Bó tiẹ̀ jẹ́ pé béèyàn ṣe lè jáwọ́ nínú lílo oògùn nílòkulò la tẹnu mọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí, àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì tó wà níbẹ̀ lè ran ẹni tó bá fẹ́ jáwọ́ nínú àwọn àṣà míì lọ́wọ́, irú bíi ọtí àmujù, sìgá, oúnjẹ àjẹjù, tẹ́tẹ́, àwòrán oníhòòhò, tàbí lílo àkókò tó pọ̀ jù lórí ìkànnì àjọlò.

b Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Wo àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?

c Ọ̀pọ̀ ilé ìwòsàn tàbí àwọn ilé ìtọ́jú míì ló lè tọ́jú ẹni tó bá fẹ́ jáwọ́ nínú àṣà èyíkéyìí. Ẹni kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu irú ìtọ́jú tóun máa gbà.​—Òwe 14:15.