Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
Ooru Tó Gbóná Janjan Mú Kárí Ayé Lọ́dún 2023—Kí Ni Bíbélì Sọ?
Nítorí ojú ọjọ́ tí kò bára dé, ibi gbogbo láyé ni ooru tó gbóná janjan àtàwọn àjálù míì ti ooru ń fà ti ń han àwọn èèyàn léèmọ̀. Ẹ kíyè si àwọn ìròyìn tó tẹ̀ lé e yìí:
“Láti nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún ó lé mẹ́rìnléláàádọ́rin (174) tí wọ́n ti ń ṣe àkọsílẹ̀ bí ojú ọjó ṣe ń móoru tó, ti oṣù June ọdún yìí ló tíì le jù.”—National Oceanic and Atmospheric Administration, U.S. Department of Commerce, July 13, 2023.
“Ooru tó gbóná janjan ń mú láwọn orílẹ̀-èdè bí Ítálì, Sípéènì, Faransé, Jámánì àti Poland, ó sì ṣeé ṣe káwọn erékùṣù tó wà ní Sicily àti Sardinia ní ojú ọjọ́ tó gbóná tó nǹkan bí 48°C [118°F.] Tí wọ́n bá fi ìwọ̀n yìí sórí nǹkan tí wọ́n fi ń díwọ̀n ooru, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òhun ni ojú ọjọ́ tó tíì gbóná jù lọ nílẹ̀ Yúróòpù.”—European Space Agency, July 13, 2023.
“Bí ojú ọjọ́ ṣe túbọ̀ ń gbóná sí i yìí, ó ṣeé ṣe kí òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá tó sì máa jẹ́ léraléra pọ̀ gan-an, èyí sì lè fa àkúnya omi tó burú gan-an.”—ọ̀gbéni Stefan Uhlenbrook, tó jẹ́ adarí ẹ̀ka hydrology, water and cryosphere ní World Meteorological Organization, July 17, 2023.
Ṣé ìròyìn lemọ́lemọ́ nipa ojú ọjọ́ tó ń gbóná gan-an yìí kàn ẹ́? Jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ nipa kókó yìí.
Ṣé ojú ọjọ́ tó ń gbóná yìí bá àṣọtẹ́lẹ̀ Bíbélì mu?
Bẹ́ẹ̀ni. Ooru tó ń mú gan-an àtàwọn ìṣòro míì tí ojú ọjọ́ tí ò dáa ń fà kárí ayé bá ohun tí Bíbélì sọ pé á máa ṣẹlẹ̀ lákòókò wa yìí mu. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé a máa rí “àwọn ohun tó ń bani lẹ́rù,” tàbí “ohun ẹ̀rù.” (Lúùkù 21:11; Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní) Bí ojú ọjọ́ ṣe túbọ̀ ń gbóná janjan kárí ayé ń mú kẹ́rù máa ba ọ̀pọ̀ pé, àwọn èèyàn máa tó ba ayé yìí jẹ́ débi tí ò fi ní ṣeé gbé mọ́.
Ṣé ìgbà kan ń bọ̀ tí ayé yìí ò ní ṣeé gbé mọ́?
Rárá. Ọlọ́run dá ayé yìí ká lè máa gbé inú rẹ̀ títí láé; kò sì ní gbà káwọn èèyàn pa á run. (Sáàmù 115:16; Oníwàásù 1:4) Kódà, ó sọ pé òun máa “run àwọn tó ń run ayé.”—Ìfihàn 11:18.
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run kò ní jẹ́ káwọ́n àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ ba ayé yìí jẹ́.
“[Ọlọ́run] mú kí ìjì náà rọlẹ̀, Ìgbì òkun sì pa rọ́rọ́.” (Sáàmù 107:29) Ọlọ́run lágbára láti kápá àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àdáyébá. Ó sì máa fòpin sí àwọn ìṣòro tí ojú ọjọ́ tí ò bára dé máa ń fà fún aráyé.
“Ò ń bójú tó ayé, O mú kí ó ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èso, kí ilẹ̀ rẹ̀ sì lọ́ràá dáadáa.” (Sáàmù 65:9) Ọlọ́run máa lo agbára ẹ̀ láti sọ ayé yìí di párádíse.
Tó o bá fẹ́ mọ sì í nípa ohun tí Bíbélì sọ lórí bí Ọlọ́run ṣe máa tún ayé yìí ṣe, wo àpilẹ̀kọ náà “Ta Ló Máa Tún Ayé Yìí Ṣe?”