À Ń Wá Òtítọ́
Wà á jáde:
1. Ẹ̀kọ́ òótọ́ ṣeyebíye;
Ìṣúra pàtàkì ló jẹ́.
Ṣùgbọ́n bí a ṣe ń wá a, à ń ṣiyèméjì,
Ọ̀pọ̀ nǹkan ni kò yé wa.
(ÌṢÁÁJÚ ÈGBÈ)
Àmọ́ kò rẹ̀ wá, À ń kẹ́kọ̀ọ́ nìṣó
Ó dá wa lójú pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tá a máa rí i.
(ÈGBÈ)
À ń wá bí a ṣe máa rí
Ìdáhùn sí àwọn
Ìbéèrè tó wà lọ́kàn wa
A fẹ́ mọ Ọlọ́run àtohun tí Ìjọba rẹ̀ máa ṣe fún wa.
À ń sapá wa gan-an.
2. A kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé Jèhófà
Ni orúkọ t’Ọlọ́run ń jẹ́.
Nígbà tá a rí i, inú wa dùn
Pé a ti ń rí ìṣúra.
(ÌṢÀÁJÚ ÈGBÈ)
À ń kẹ́kọ̀ọ́ nìṣó, a ò jẹ́ kó sú wa.
A fẹ́ mọ bá a ṣe dáyé àti bọ́la ṣe máa rí.
(ÈGBÈ)
À ń wá bí a ṣe máa rí
Ìdáhùn sí àwọn
Ìbéèrè tó wà lọ́kàn wa
A fẹ́ mọ Ọlọ́run àti bí Párádísè tó ṣèlérí ṣe máa rí.
À ń wá a, a ó sì rí i.
(ÀSOPỌ̀)
Ó yẹ kí á ṣèrànwọ́ fún àwọn èèyàn yìí
Bí wọ́n ṣe ń wá òtítọ́.
Ọ̀pọ̀ nǹkan wà tí kò yé wọn rárá.
Ẹ jẹ́ ká fọ̀nà hàn wọ́n.
Ká fohun tá a ti kọ́ hàn wọ́n.
(ÈGBÈ)
Wọ́n ń wá bí wọ́n ṣe máa rí
Ìdáhùn sí àwọn
Ìbéèrè tó wà lọ́kàn wọn
Wọ́n fẹ́ mọ Ọlọ́run àti bí ìyè àìnípẹ̀kun ṣe máa rí.
Ẹ wá a, ẹ ó sì rí i.