ORIN 101
À Ń Ṣiṣẹ́ Níṣọ̀kan
-
1. Ọlọ́run ti yà wá sọ́tọ̀
Nínú ayé burúkú yìí.
Ó fi wá sínú ètò rẹ̀
Ká lè wà lálàáfíà.
À ń ṣiṣẹ́ níṣọ̀kan;
Ó dára, ó dùn!
Jèhófà ti yan Ọmọ rẹ̀
Láti darí iṣẹ́ tá à ń ṣe.
A gbọ́dọ̀ jẹ́ onígbọràn.
Ká ṣiṣẹ́ nírẹ̀ẹ́pọ̀.
-
2. À ń gbàdúrà s’Ọ́lọ́run pé
Kíṣọ̀kan gbilẹ̀ láàárín wa.
Yóò mú kífẹ̀ẹ́ wa gbòòrò sí i,
Ká sì túbọ̀ láyọ̀.
Àlàáfíà wa ń pọ̀ sí i,
Ó ń mára tù wá.
Jèhófà yóò máa bù kún wa
Bá a ṣe ń fi ìfẹ́ tòótọ́ hàn.
Yóò mú ká máa wà níṣọ̀kan.
A ó máa sìn ín títí láé.
(Tún wo Míkà 2:12; Sef. 3:9; 1 Kọ́r. 1:10.)