Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Hébérù 4:12—“Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Yè, Ó sì Ní Agbára”

Hébérù 4:12—“Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Yè, Ó sì Ní Agbára”

 “Torí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà láàyè, ó sì ní agbára, ó mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ, ó sì ń gúnni, àní débi pé ó ń pín ọkàn àti ẹ̀mí níyà, ó ń pín àwọn oríkèé àti mùdùnmúdùn sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, ó sì lè mọ ìrònú àti ohun tí ọkàn ń gbèrò.”​—Hébérù 4:12, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ní agbára, ó sì mu ju idàkídà olójú méjì lọ, ó sì ń gún ni, àní títí dé pínpín ọkàn àti ẹ̀mí ní yà, àti ní oríkèé àti ọ̀rá inú egungun, òun sì ni olùmọ̀ èrò inú àti ète ọkàn.”​—Hébérù 4:12, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní.

Ìtumọ̀ Hébérù 4:12

 Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run bá wa sọ ló wà nínú Bíbélì, ó sì lágbára láti fi irú ẹni tá a jẹ́ hàn àti ohun tó ń sún wa ṣe nǹkan. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń tún ayé èèyàn ṣe.

 “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà láàyè.” “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” tí ẹsẹ yìí ń sọ tọ́ka sí àwọn ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì tàbí àwọn ohun tí Ọlọ́run pinnu láti ṣe. a Ọ̀kan nínú àwọn ìlérí tó ṣe pàtàkì ni èyí tí Ọlọ́run ṣe pé, àwọn tó bá ṣe ìfẹ́ òun máa gbé ayé títí láé, wọ́n á sì máa gbé pa pọ̀ láyọ̀ àti àlàáfíà.​—Jẹ́nẹ́sísì 1:28; Sáàmù 37:29; Ìfihàn 21:3, 4.

 Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “wà láàyè”? Ìdí ni pé ọkàn àwọn tó bá gbà á gbọ́ máa ń balẹ̀ pé ọlà ń bọ̀ wá dáa, ìyẹn sì ń jẹ́ káyé wọn nítumọ̀. (Diutarónómì 30:14; 32:47) Àwọn ìlérí Ọlọ́run náà “wà láàyè” ní ti pé Ọlọ́run alààyè ló ṣe wọ́n, Ọlọ́run ò sì ṣíwọ́ láti ṣe ohun táá mú kí àwọn ìlérí náà ṣẹ. (Jòhánù 5:17) Ọlọ́run ò dà bí àwa èèyàn tó máa ń gbàgbé nǹkan, kò ní gbàgbé àwọn ìlérí rẹ̀ tàbí kó sọ pé òun ò lágbára láti mú un ṣẹ. (Nọ́ńbà 23:19) Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ “kò ní pa dà sọ́dọ̀ [rẹ̀] láìṣẹ.”​—Àìsáyà 55:10, 11.

 “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run . . . ní agbára.” Ọ̀rọ̀ náà “ní agbára” tún lè túmọ̀ sí “gbéṣẹ́” tàbí pé “kò sí ohun tó lè dí i lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó fẹ́.” Torí náà, tí Jèhófà b Ọlọ́run bá sọ̀rọ̀ kan tàbí tó ṣèlérí kan, ó dájú pé ó máa ṣẹ. (Sáàmù 135:6; Àìsáyà 46:10) Ọlọ́run lè mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ ju bá a ṣe rò lọ.​—Éfésù 3:20. c

 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún “ní agbára,” torí ó lè mú kí àwọn tó mọyì rẹ̀ ṣe àwọn àtúnṣe tó bá yẹ nínú ìwà àti ìṣe wọn. Torí pé wọ́n fara mọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó ti jẹ́ kí wọ́n yí bí wọ́n ṣe ń ronú pa dà, títí kan bí wọ́n ṣe ń gbé ìgbé ayé wọn àti ohun tí wọ́n fẹ́ fayé wọn ṣe. (Róòmù 12:2; Éfésù 4:24) Nípa bẹ́ẹ̀, “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run . . . wà lẹ́nu iṣẹ́ nínú” àwọn tó gbà pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni lóòótọ́.​—1 Tẹsalóníkà 2:13.

 “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run . . . mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ.” Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí táwa èèyàn ṣe lọ, torí pé ó máa ń wọni lọ́kàn ṣinṣin. Ìyẹn ni pé ó máa ń jẹ́ ká mọ irú ẹni tá a jẹ́ gan-an, kò sì sí ẹ̀kọ́ ìwé kankan tó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Èyí ṣe kedere nínú ohun tí Hébérù 4:12 sọ tẹ̀ lé e.

 “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run . . . ń gúnni, àní débi pé ó ń pín ọkàn àti ẹ̀mí níyà, ó ń pín àwọn oríkèé àti mùdùnmúdùn sọ́tọ̀ọ̀tọ̀.” Nínú Bíbélì, “ọkàn” máa ń tọ́ka sí ohun tí ẹnì kan rò pé òun jẹ́, “ẹ̀mí” sì ń tọ́ka sí ohun tí ẹnì kan jẹ́ gan-an ní inú. (Gálátíà 6:18) Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” máa ń wọni lára débi pé ó máa ń wọnú “mùdùnmúdùn,” ìyẹn ohun tá à ń rò nínú ọkàn wa lọ́hùn-ún àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa. Ẹ̀kọ́ Bíbélì máa ń jẹ́ ká mọ irú ẹni tá a jẹ́ gan-an ní inú, níbi tí ojú ẹ̀dá ò lè tó, ìyẹn á jẹ́ ká lè ṣe àwọn àtúnṣe tó bá yẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, a máa láyọ̀, àá sì múnú Ẹlẹ́dàá wa dùn.

 “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run . . . lè mọ ìrònú àti ohun tí ọkàn ń gbèrò.” Ohun tẹ́nì kan bá ṣe lẹ́yìn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa jẹ́ ká mọ ohun tó ń rò lọ́kàn àti ìdí tó fi ń ṣe ohun tó ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, tẹ́nì kan bá ṣe àwọn àyípadà tó yẹ lẹ́yìn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn máa fi hàn pé ó lọ́kàn tó dáa, ó nírẹ̀lẹ̀, ó sì fẹ́ ṣe ohun tínú Ọlọ́run dùn sí. Lọ́wọ́ kejì, tẹ́nì kan bá ń ṣàwáwí lẹ́yìn tó gbọ́rọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn fi hàn pé kò lọ́kàn tó dáa, ó ní ìgbéraga, tara ẹ̀ nìkan ló sì mọ̀. Ṣe ni irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń wá àwíjàre láti ṣe ohun tínú Ọlọ́run ò dùn sí.​—Jeremáyà 17:9; Róòmù 1:24-27.

 Bí ìwé ìwádìí kan ṣe sọ ló rí pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “lè ní ipa lórí gbogbo apá ìgbésí ayé wa.” kò sóhun tẹ́nì kan lè máa rò lọ́kàn tó pa mọ́ lójú Ọlọ́run tàbí tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ò lè tan ìmọ́lẹ̀ sí. Hébérù 4:13 sọ pé: “Ohun gbogbo wà ní ìhòòhò, ó sì wà ní gbangba lójú ẹni tí a gbọ́dọ̀ jíhìn fún.”

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Hébérù 4:12

 Lọ́dún 61 Sànmánì Kristẹni, Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ ohun tó wà nínú ìwé Hébérù sáwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà.

 Ní orí 3 àti 4, Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká rí i pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ jẹ́ ìkìlọ̀ fáwa Kristẹni òde òní. (Hébérù 3:8-12; 4:11) Nígbà yẹn, Jèhófà ṣèlérí fún wọn pé òun máa dá wọn sílẹ̀ lóko ẹrú, wọ́n á jogún Ilẹ̀ Ìlérí, wọ́n á sì máa “gbé láìséwu” níbẹ̀. (Diutarónómì 12:9, 10) Ó bani nínú jẹ́ pé, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kúrò ní Íjíbítì kò nígbàgbọ́ pé àwọn ìlérí Jèhófà máa ṣẹ, abájọ tí wọ́n fi ń ṣàìgbọràn léraléra. Ohun tí wọ́n ṣe yìí ni ò jẹ́ kí wọn “wọnú ìsinmi [Ọlọ́run],” wọn ò sì gbádùn àwọn ìbùkún Jèhófà. Ṣe ni wọ́n kú sínú aginjù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn àtọmọdọ́mọ wọn wọ Ilẹ̀ Ìlérí, kò pẹ́ táwọn náà fi di aláìgbọràn. Nígbà tó yá, Jèhófà pa gbogbo orílẹ̀-èdè náà tì pátápátá.​—Nehemáyà 9:29, 30; Sáàmù 95:9-11; Lúùkù 13:34, 35.

 Pọ́ọ̀lù wá gba àwọn Kristẹni nímọ̀ràn pé kí wọ́n fi ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìgbọràn yìí ṣe àríkọ́gbọ́n. Lónìí, tá a bá fẹ́ wọnú ìsinmi Ọlọ́run, á gbọ́dọ̀ jẹ́ onígbọràn, ká sì jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ.​—Hébérù 4:1-3, 11.

 Wo fídíò yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé Hébérù.

a Ọ̀rọ̀ náà, “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” tó wà nínú Hébérù 4:12 kò tọ́ka sí Bíbélì ní tààràtà. Síbẹ̀ inú Bíbélì làwọn ìlérí Ọlọ́run wà. Torí náà, a ṣì lè lo Hébérù 4:12 láti tọ́ka sí Bíbélì.

b Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Ka àpilẹ̀kọ náà “Ta ni Jèhófà?