Ṣé Aṣọ Ìsìnkú Turin Ni Wọ́n Fi Sin Òkú Jésù?
Ohun tí Bíbélì sọ
Bíbélì ò dárúkọ Aṣọ Ìsìnkú Turin. Aṣọ ọ̀gbọ̀ ni aṣọ yìí, ọ̀pọ̀ ló sì rò pé òun ni wọ́n fi sin òkú Jésù Kristi. Torí èyí làwọn kan ṣe gbà pé ọ̀kan lára àwọn ohun ìṣẹ̀nbáyé mímọ́ jù lọ tó jẹ́ ti Kristẹndọmu ni aṣọ ìsìnkú yìí. Ṣọ́ọ̀ṣì kan tó wà nílùú Turin, lórílẹ̀-èdè Ítálì ni aṣọ ìsìnkú yìí wà báyìí, inú àpótí ìgbàlódé kan tí wọ́n tì gbọn-in gbọn-in ni wọ́n gbé e sí.
Ṣé Bíbélì jẹ́rìí sí i pé Aṣọ Ìsìnkú Turin ni wọ́n fi sin Jésù lóòótọ́? Rárá o.
Wo nǹkan mẹ́ta nípa aṣọ náà tó yàtọ̀ sí ohun tí Bíbélì sọ.
Aṣọ kan ṣoṣo ni aṣọ ìsìnkú náà, gígùn rẹ̀ lé ní mítà mẹ́rin, fífẹ̀ rẹ̀ sì lé ní mítà kan, wọ́n wá rán okùn oní sẹ̀ǹtímítà mẹ́jọ kan mọ́ ọn níbi ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ gígùn.
Ohun tí Bíbélì sọ: Kì í ṣe aṣọ ọ̀gbọ̀ kan ṣoṣo ni wọ́n fi wé òkú Jésù, ọ̀pọ̀ aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́ tẹ́ẹ́rẹ́ ni wọ́n fi dì í. Ọ̀tọ̀ sì ni aṣọ tí wọ́n fi wé orí rẹ̀. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ọ̀kan nínú àwọn àpọ́sítélì náà wá síbi ibojì tó ṣófo, ó sì “rí àwọn ọ̀já ìdìkú náà nílẹ̀.” Bíbélì fi kún un pé: “Aṣọ tí ó ti wà ní orí rẹ̀ kò sí nílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀já ìdìkú náà ṣùgbọ́n a ká a jọ sọ́tọ̀ ní ibì kan.”—Jòhánù 20:6, 7.
Aṣọ ìsìnkú náà ní ohun tó jọ ẹ̀jẹ̀ lára, wọ́n gbà pé wọn ò fọ ara òkú tí wọ́n fi sin.
Ohun tí Bíbélì sọ: Nígbà tí Jésù kú, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe òkú rẹ̀ “gẹ́gẹ́ bí àwọn Júù ti ní àṣà mímúra sílẹ̀ fún ìsìnkú.” (Jòhánù 19:39-42) Ara àṣà àwọn Júù ni pé kí wọ́n fọ òkú, kí wọ́n sì fi òróró àti èròjà atasánsán sí òkú náà lára kí wọ́n tó sin ín. (Mátíù 26:12; Ìṣe 9:37) Torí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ti ní láti fọ òkú rẹ̀ kí wọ́n tó fi aṣọ wé e.
Aṣọ ìsìnkú náà ní àwòrán ọkùnrin kan “tí wọ́n tẹ́ gbọọrọ sínú ìdajì aṣọ náà, tí wọ́n wá da ìdajì yòókù bò ó níwájú títí dé orí,” bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica ṣe sọ ọ́.
Ohun tí Bíbélì sọ: Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ̀rọ̀ nípa ikú rẹ̀, ibojì rẹ̀ tó ṣófo, àti ohun táwọn obìnrin tó fojú ara wọn rí “ìran kan tí ó ju ti ẹ̀dá lọ, tí ó jẹ́ ti àwọn áńgẹ́lì, tí wọ́n sọ pé ó wà láàyè” wá jábọ̀ fún wọn. (Lúùkù 24:15-24) Ká ní lóòótọ́ ni aṣọ ìsìnkú yẹn wà nínú ibojì Jésù, ó dájú pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ì bá ti sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ àti àwòrán tó wà lára ẹ̀. Àmọ́ Bíbélì ò sọ nǹkan kan tó jọ bẹ́ẹ̀.
Ṣé ó yẹ ká máa júbà aṣọ ìsìnkú yìí?
Rárá. Kódà, kó jẹ́ pé òun ni wọ́n fi sin Jésù lóòótọ́, kò tọ́ tá a bá ń júbà rẹ̀. Wo àwọn ìlànà Bíbélì kan tó ṣàlàyé ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀.
Kò pọn dandan. Jésù sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí, àwọn tí ń jọ́sìn rẹ̀ sì gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:24) Àwọn tó bá ń ṣe ìjọsìn tòótọ́ kì í lo àwọn ohun ìṣẹ̀nbáyé tàbí ère tó jẹ mọ́ ẹ̀sìn tí wọ́n bá ń jọ́sìn.
Ọlọ́run dẹ́bi fún un. Òfin Mẹ́wàá dẹ́bi fún ìbọ̀rìṣà. (Diutarónómì 5:6-10) Bẹ́ẹ̀ náà ni Bíbélì ṣe pàṣẹ fáwọn Kristẹni pé: “Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn òrìṣà.” (1 Jòhánù 5:21) Àwọn míì lè sọ pé lójú tàwọn, aṣọ ìsìnkú yẹn kì í ṣe ère, pé àmì ohun kan táwọn gbà gbọ́ ni. Àmọ́ téèyàn bá ti ń júbà nǹkan tó kà sí àmì ohun tó gbà gbọ́, ó ti di ère nìyẹn. a Torí náà, ẹni tó bá fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn ò ní fi ìjọsìn fún ohunkóhun, títí kan aṣọ ìsìnkú náà, tàbí kó júbà rẹ̀.
a Ère ni àwòrán tàbí àmì ohun kan téèyàn ń lò nínú ìjọsìn.