Àwọn Wo Là Ń Pè Ní Áńgẹ́lì?
Ohun tí Bíbélì sọ
Ẹ̀dá tó lágbára gan-an, tó sì ju àwọn èèyàn lọ ni àwọn áńgẹ́lì. (2 Pétérù 2:11) Ọ̀run ni wọ́n ń gbé, ibẹ̀ ò ṣeé fojú rí, ó sì yàtọ̀ pátápátá sí àgbáyé wa yìí. (1 Àwọn Ọba 8:27; Jòhánù 6:38) Ìdí nìyẹn tá a tún fi ń pe àwọn áńgẹ́lì ní ẹ̀dá ẹ̀mí.—1 Àwọn Ọba 22:21; Sáàmù 18:10.
Ibo làwọn áńgẹ́lì ti wá?
Jésù, tí Bíbélì pè ní “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá” ni Ọlọ́run lò láti dá àwọn áńgẹ́lì. Bíbélì sọ bí Ọlọ́run ṣe lo Jésù láti dá àwọn nǹkan, ó ní: “Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá gbogbo ohun mìíràn ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé, àwọn ohun tí a lè rí àti àwọn ohun tí a kò lè rí,” títí kan àwọn áńgẹ́lì. (Kólósè 1:13-17) Àwọn áńgẹ́lì kì í fẹ́yàwó, wọn kì í sì í bímọ. (Máàkù 12:25) Ìkọ̀ọ̀kan ni wọ́n dá “àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́” yìí.—Jóòbù 1:6.
Ọjọ́ pẹ́ tí Ọlọ́run ti dá àwọn áńgẹ́lì, kó tó dá ayé pàápàá. Nígbà tí Ọlọ́run dá ayé, àwọn áńgẹ́lì “bẹ̀rẹ̀ sí hó yèè nínú ìyìn.”—Jóòbù 38:4-7.
Áńgẹ́lì mélòó ló wà?
Bíbélì ò sọ iye kan pàtó, àmọ́ ó jẹ́ ká mọ̀ pé wọ́n pọ̀ gan-an. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Jòhánù rí ìran kan nípa ọgọ́rọ̀ọ̀rún mílíọ̀nù àwọn áńgẹ́lì.—Ìṣípayá 5:11.
Ṣé gbogbo áńgẹ́lì ló yàtọ̀ síra, tí kálukú wọn sì ní orúkọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀?
Bẹ́ẹ̀ ni. Bíbélì dárúkọ àwọn áńgẹ́lì méjì: Máíkẹ́lì and Gébúrẹ́lì. (Dáníẹ́lì 12:1; Lúùkù 1:26) a Àwọn áńgẹ́lì míì gbà pé àwọn lórúkọ, àmọ́ wọn ò sọ ọ́.—Jẹ́nẹ́sísì 32:29; Àwọn Onídàájọ́ 13:17, 18.
Àwọn áńgẹ́lì yàtọ̀ síra. Wọ́n máa ń bára wọn sọ̀rọ̀. (1 Kọ́ríńtì 13:1) Wọ́n máa ń ronú, wọ́n sì lè fi ọ̀rọ̀ yin Ọlọ́run. (Lúùkù 2:13, 14) Wọ́n tún lómìnira láti yan ohun tó tọ́ tàbí èyí tí ò tọ́, a rí àpẹẹrẹ irú ẹ̀ nígbà tí àwọn kan lára wọn ṣẹ̀, tí wọ́n dara pọ̀ mọ́ Sátánì Èṣù nígbà tó dìtẹ̀ sí Ọlọ́run.—Mátíù 25:41; 2 Pétérù 2:4.
Ṣé ipò àwọn áńgẹ́lì máa ń jura wọn?
Bẹ́ẹ̀ ni. Áńgẹ́lì tó lágbára jù, tó sì láṣẹ jù ni Máíkẹ́lì, olú-áńgẹ́lì. (Júúdà 9; Ìṣípayá 12:7) Áńgẹ́lì tí ipò wọn ga ni àwọn séráfù, ẹ̀gbẹ́ ìtẹ́ Jèhófà ni wọ́n máa ń wà. (Aísáyà 6:2, 6) Àwọn áńgẹ́lì míì tí ipò wọn ga ni àwọn kérúbù, wọ́n ní iṣẹ́ àrà ọ̀tọ̀ tí wọ́n ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kérúbù ló ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ọgbà Édẹ́nì lẹ́yìn tí Ọlọ́run lé Ádámù àti Éfà jáde.—Jẹ́nẹ́sísì 3:23, 24.
Ṣé àwọn áńgẹ́lì máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́?
Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run ń fi àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ olóòótọ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ lónìí.
Ọlọ́run ń lo àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ bó ṣe ń darí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ń wàásù ìròyìn ayọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. (Ìṣípayá 14:6, 7) Bí Ọlọ́run ṣe ń darí iṣẹ́ yìí ń ṣe àwọn tó ń wàásù àtàwọn tó ń gbọ́ ìhìn rere náà láǹfààní.—Ìṣe 8:26, 27.
Àwọn áńgẹ́lì máa ń dáàbò bo ìjọ Kristẹni káwọn ẹni burúkú má bàa kó èèràn ran àwọn èèyàn Ọlọ́run.—Mátíù 13:49.
Àwọn áńgẹ́lì máa ń dáàbò bo àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run, wọ́n sì máa ń tọ́ wọn sọ́nà.—Sáàmù 34:7; 91:10, 11; Hébérù 1:7, 14.
Àwọn áńgẹ́lì máa mú ìtura bá aráyé láìpẹ́, nígbà tí àwọn àti Jésù Kristi bá jagun tó máa fòpin sí ìwà burúkú.—2 Tẹsalóníkà 1:6-8.
Ṣé gbogbo wa la ní áńgẹ́lì kọ̀ọ̀kan tó ń dáàbò bò wá?
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn áńgẹ́lì máa ń ran àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́ lẹ́nu ìjọsìn wọn, kò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run yan áńgẹ́lì kan kó máa ṣọ́ Kristẹni kọ̀ọ̀kan. b (Mátíù 18:10) Kì í ṣe gbogbo àdánwò tàbí ìṣòro ni àwọn áńgẹ́lì ti máa ń kó àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run yọ. Bíbélì sọ pé láwọn ìgbà míì, ṣe ni Ọlọ́run máa ń “ṣe ọ̀nà àbájáde” fún wa nínú ìṣòro ní ti pé ó máa ń fún wa lọ́gbọ́n àti okun láti fara da ìṣòro náà.—1 Kọ́ríńtì 10:12, 13; Jákọ́bù 1:2-5.
Èrò tí kò tọ́ táwọn èèyàn ní nípa àwọn áńgẹ́lì
Èrò tí kò tọ́: Ẹni rere ni gbogbo àwọn áńgẹ́lì.
Òótọ́: Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa “àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú” àti “àwọn áńgẹ́lì tí ó ṣẹ̀.” (Éfésù 6:12; 2 Pétérù 2:4) Àwọn áńgẹ́lì burúkú yìí ni àwọn ẹ̀mí èṣù tó dara pọ̀ mọ́ Sátánì nígbà tó ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run.
Èrò tí kò tọ́: Àwọn áńgẹ́lì ò lè kú.
Òótọ́: Àwọn áńgẹ́lì burúkú, títí kan Sátánì Èṣù, máa pa run.—Júúdà 6.
Èrò tí kò tọ́: Àwọn èèyàn máa ń di áńgẹ́lì tí wọ́n bá ti kú.
Òótọ́: Ọ̀tọ̀ ni Ọlọ́run dá àwọn áńgẹ́lì, wọ́n yàtọ̀ sí àwọn èèyàn tó jíǹde. (Kólósè 1:16) Ọlọ́run máa ń sọ àwọn tó bá jíǹde sí ọ̀run di ẹni tí ò lè kú mọ́. (1 Kọ́ríńtì 15:53, 54) Ipò wọn máa ju tàwọn áńgẹ́lì lọ.—1 Kọ́ríńtì 6:3.
Èrò tí kò tọ́: Torí kí àwọn áńgẹ́lì lè máa sin àwọn èèyàn ni wọ́n ṣe wà.
Òótọ́: Àṣẹ Ọlọ́run làwọn áńgẹ́lì ń tẹ̀ lé, kì í ṣe tàwa èèyàn. (Sáàmù 103:20, 21) Jésù gan-an gbà pé Ọlọ́run ló yẹ kóun pè fún ìrànlọ́wọ́, kì í ṣe àwọn áńgẹ́lì.—Mátíù 26:53.
Èrò tí kò tọ́: A lè gbàdúrà sí àwọn áńgẹ́lì pé kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́.
Òótọ́: Ara ìjọsìn wa, tó tọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run, ni pé ká máa gbàdúrà sí i. (Ìṣípayá 19:10) Ọlọ́run nìkan ló yẹ ká máa gbàdúrà sí, ká sì ṣe bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ Jésù.—Jòhánù 14:6.
a Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan lo ọ̀rọ̀ náà “Lúsíférì” ní Aísáyà 14:12, èyí tí àwọn kan máa ń kà sí orúkọ áńgẹ́lì tó di Sátánì Èṣù. Àmọ́, “ẹni tí ń tàn” ni ọ̀rọ̀ Hébérù tí Bíbélì lò níbí túmọ̀ sí. Àwọn ẹsẹ tó ṣáájú àtèyí tó tẹ̀ lé e fi hàn pé kì í ṣe Sátánì ni ọ̀rọ̀ yẹn ń tọ́ka sí, àmọ́ alákòóso orílẹ̀-èdè Bábílónì, tí Ọlọ́run máa tó sọ di ẹni ilẹ̀ torí ìgbéraga rẹ̀ ni ọ̀rọ̀ náà ń tọ́ka sí. (Aísáyà 14:4, 13-20) Wọ́n fi ọ̀rọ̀ náà, “ẹni tí ń tàn” kẹ́gàn alákòóso Bábílónì lẹ́yìn tí wọ́n ṣẹ́gun rẹ̀.
b Àwọn kan sọ pé ìtàn tó dá lórí bí áńgẹ́lì kan ṣe dá Pétérù sílẹ̀ lẹ́wọ̀n fi hàn pé Pétérù ní áńgẹ́lì kan tó ń dáàbò bò ó. (Ìṣe 12:6-16) Àmọ́ nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn sọ pé “áńgẹ́lì [Pétérù]” ni, ó lè jẹ́ pé ṣe ni wọ́n rò pé áńgẹ́lì kan tó ń ṣojú fún Pétérù ló wá sọ́dọ̀ wọn, kì í ṣe Pétérù fúnra ẹ̀.