Ǹjẹ́ Bíbélì Sọ̀rọ̀ Nípa Ìgbéyàwó Láàárín Ọkùnrin àti Ọkùnrin Tàbí Láàárín Obìnrin àti Obìnrin?
Ohun tí Bíbélì sọ
Ẹlẹ́dàá wa ti jẹ́ káwọn èèyàn mọ àwọn òfin tó de ìgbéyàwó tipẹ́ kí àwọn ìjọba tó bẹ̀rẹ̀ sí í gbé òfin kalẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó. Ìwé àkọ́kọ́ nínú Bíbélì sọ fún wa pé: “Ọkùnrin yóò . . . fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ tí yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Ìwé atúmọ̀ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì kan sọ pé ọ̀rọ̀ náà “aya” lédè Hébérù “ń tọ́ka sí obìnrin.” Jésù mú kó ṣe kedere pé “akọ àti abo” ni a gbọ́dọ̀ máa so pọ̀ nínú ìgbéyàwó.—Mátíù 19:4.
Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé kí ìgbéyàwó wà títí lọ, kí ó sì jẹ́ láàárín ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin lọ́nà tí wọ́n á fi lè jẹ́ àṣekún ara wọn, kí wọ́n lè fi ara wọn lọ́kàn balẹ̀, kí wọ́n lè ní ìbálòpọ̀, kí wọ́n sì lè bímọ.