Báwo Ni Èṣù Ṣe Rí?
Ohun Tí Bíbélì Sọ
Èṣù jẹ́ ẹni ẹ̀mí tí kò ṣeé fojú rí, ìyẹn ni pé kò rí bí àwa èèyàn.—Éfésù 6:11, 12.
Àwọn èèyàn sábà máa ń ya àwòrán èṣù bíi pé ojú rẹ̀ dà bí ti ewúrẹ́ tó ní ìwo lórí, tó ní ìrù, tó sì gbé àmúga kan lọ́wọ́. Àwọn kan gbà pé àwọn ayàwòrán tó gbé láyé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan ọdún sẹ́yìn ló ya àwòrán èṣù bẹ́ẹ̀ torí ìtàn àròsọ àti ìtàn àtẹnudẹ́nu tí wọ́n gbọ́.
Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe Èṣù?
Oríṣiríṣi ọ̀nà ni Bíbélì gbà ṣàlàyé èṣù, kì í ṣe nítorí ká lè mọ ìrísí èṣù, àmọ́ ká lè mọ irú ẹni tó jẹ́. Lára irú àwọn àfiwéra bẹ́ẹ̀ ni:
Áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀. Ó máa ń dọ́gbọ́n fi àwọn ohun tó dà bí ohun rere fa ojú àwọn èèyàn mọ́ra kí wọ́n lè máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀ dípò kí wọ́n máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.—2 Kọ́ríńtì 11:14.
Kìnnìún tó ń ké ramúramù. Ó máa ń fi ìbínú gbéjà ko àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run.—1 Pétérù 5:8.
Dírágónì ńlá. Àkòtagìrì ni, ó lágbára, ó sì ń pani run.—Ìfihàn 12:9..