Kí Ni Ọlọ́run Fẹ́ Kí N Fi Ayé Mi Ṣe?
Ohun tí Bíbélì sọ
Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé kó o mọ Ẹni tí òun jẹ́, kó o sún mọ́ òun, kó o nífẹ̀ẹ́ òun, kó o sì máa sin òun pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ. (Mátíù 22:37, 38; Jákọ́bù 4:8) O lè kọ́ bí wàá ṣe máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tó o bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù àti àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀. (Jòhánù 7:16, 17) Jésù ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe. Kódà, Jésù sọ pé ìdí tí òun fi wá sáyé kì í ṣe “láti ṣe ìfẹ́ mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi.”—Jòhánù 6:38.
Ǹjẹ́ mo nílò kí Ọlọ́run fi àmì àrà ọ̀tọ̀ kan hàn mí, kí n rí ìran tàbí kó bá mi sọ̀rọ̀ kí n tó mọ bí màá ṣe máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀?
Rárá o! Ìdí ni pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe wà nínú Bíbélì. Inú rẹ̀ ni a ó ti rí ohun tó máa jẹ́ ká lè “gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.” (2 Tímótì 3:16, 17) Ọlọ́run fẹ́ kó o máa ka Bíbélì, kó o sì máa lo “agbára ìmọnúúrò” rẹ kó o lè mọ ohun tí ìfẹ́ rẹ̀ jẹ́.—Róòmù 12:1, 2; Éfésù 5:17.
Ǹjẹ́ mo lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lóòótọ́?
Bẹ́ẹ̀ ni, o lè ṣe é, torí Bíbélì sọ pé: “Àwọn àṣẹ [Ọlọ́run] kì í ṣe ẹrù ìnira.” (1 Jòhánù 5:3) Àmọ́, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé gbogbo ìgbà ni pípa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́ yóò máa rọ̀ wá lọ́rùn. Ṣùgbọ́n àǹfààní tó wà nínú pípa wọ́n mọ́ tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!”—Lúùkù 11:28.