Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Fífúnni?
Ohun tí Bíbélì sọ
Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká máa fúnni látọkàn wá láìretí ohunkóhun pa dà. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé àwa àtẹni tá a fún ní nǹkan máa láyọ̀. (Òwe 11:25; Lúùkù 6:38) Jésù sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.
Báwo ni Ọlọ́run ṣe fẹ́ ká máa fúnni?
Tá a bá ń fúnni látọkàn wá, a máa láyọ̀. Bíbélì sọ pé: “Kí kálukú ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú lílọ́ra tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ẹni tó ń fúnni pẹ̀lú ìdùnnú.”—2 Kọ́ríńtì 9:7.
Fífúnni látọkàn wá jẹ́ apá kan “Ìjọsìn tó mọ́” tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà. (Jémíìsì1:27) Ńṣe ni ẹni tó bá lawọ́ sí àwọ́n aláìní ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run , Ọlọ́run máa ń wo irú oore bẹ́ẹ̀ bí ìgbà tá a yá òun ní nǹkan. (Òwe 19:17) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa san onítọ̀hún lẹ́san.—Lúùkù 14:12-14.
Ọ̀nà wo ni Ọlọ́run ò fẹ́ ká máa gbà fúnni?
Tó bá jẹ́ pé torí àǹfààní ara wa nìkan la ṣe ń fúnni. Bí àpẹẹrẹ:
Torí káwọn èèyàn lè yìn wá.—Mátíù 6:2.
Torí ohun tá a máa gbà pa dà.—Lúùkù 14:12-14.
Ká baà lè rí ìgbàlà.—Sáàmù 49:6, 7.
Tó bá jẹ́ pé ohun tá a fẹ́ fún ẹnì kan máa ti àwọn àṣà tàbí ìwà tínú Ọlọ́run ò dùn sí lẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, kò ní bọ́gbọ́n mu tá a bá fún ẹnì kan lówó kó fi ta tẹ́tẹ́, kó fi ra oògùn tàbí ọtí tó fẹ́ lò nílòkulò. (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; 2 Kọ́ríńtì 7:1) Bákan náà, tẹ́nì kan bá lè gbọ́ bùkátà ara rẹ̀ àmọ́ tí ò kọ̀ láti ṣiṣẹ́, kò yẹ ká fún un ní nǹkan.— Tẹsalóníkà 3:10.
Tí kò bá ní jẹ́ ká ráyè fún ìdílé wa. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn olórí ìdílé gbọ́dọ̀ máa pèsè fún ìdílé wọn. (1 Tímótì 5:8) Kò yẹ kí àwọn olórí ìdílé máa kóyán ìdílé wọn kéré torí pé wọ́n fẹ́ lawọ́ sí àwọn míì. Kódà, Jésù dẹ́bi fún àwọn tó kọ̀ láti bójú tó àwọn òbí wọn tó ti di àgbàlagbà torí wọ́n sọ pé gbogbo nǹkan tí àwọn ní jẹ́ “ẹ̀bùn tí a yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run.”.—Máàkù 7:9-13.