Ṣé Ó Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Máa Pa Sábáàtì Mọ́?
Ohun tí Bíbélì sọ
Kò yẹ kí àwọn Kristẹni máa pa sábáàtì mọ́. “Òfin Kristi” làwọn Kristrẹni ń tẹ̀ lé, kó sì sí nínú òfin náà pé kí wọ́n pa Sábáàtì mọ́. (Gálátíà 6:2; Kólósè 2:16, 17) Kí ló mú kí èyí dá wa lójú? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, gbé ìbi tí Sábáàtì ti ṣẹ̀ wá yẹ̀ wò.
Kí ni Sábáàtì?
Ọ̀rọ̀ náà “sábáàtì” wá látinú èdè Hébérù tó túmọ̀ sí “sinmi; dáwọ́ dúró.” Inú òfin tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ gbà Ió sì ti kọ́kọ́ fara hàn. (Ẹ́kísódù 16:23) Bí àpẹẹrẹ, òfin kẹrin nínú Òfin Mẹ́wàá sọ pé: “Máa rántí ọjọ́ sábáàtì láti kà á sí ọlọ́wọ̀, kí ìwọ ṣe iṣẹ́ ìsìn, kí o sì ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ ní ọjọ́ mẹ́fà. Ṣùgbọ́n ọjọ́ keje jẹ́ sábáàtì fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí.” (Ẹ́kísódù 20:8-10) Ọjọ́ Sábáàtì bẹ̀rẹ̀ látìgbà tí oòrùn bá ti wọ̀ nírọ̀lẹ́ Friday títí di ìrọ̀lẹ́ Saturday nígbà tí oòrùn bá wọ̀. Ní àsìkò yìí, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò gbọ́dọ̀ jáde kúrò ní àdúgbò wọn, wọn kò gbọdọ̀ dá iná, wọn kò gbọdọ̀ ṣa igi jọ, tàbí gbé ẹrù. (Ẹ́kísódù 16:29; 35:3; Númérì 15:32-36; Jeremáyà 17:21) Ẹ̀ṣẹ̀ tó búrú jáì ni ẹni tó bá rú òfin Sábáàtì dá.—Ẹ́kísódù 31:15.
Nínú kàlẹ́ńdà àwọn Júù, wọ́n tún máa ń pe àwọn ọdún bí ọdún keje àti àádọ́ta ọdún ní sábáàtì. Ní àwọn ọdún Sábáàtì, wọn kò gbọ́dọ̀ fún irúgbìn sí pápá wọn tàbí kí wọ́n fipá mú kí ọmọ Isírẹ́lì bíi tiwọn san gbèsè tó jẹ wọ́n.—Léfítíkù 16:29-31; 23:6, 7, 32; 25:4, 11-14; Diutarónómì 15:1-3.
Kí nìdí tí òfin Sábáàtì kò fi wúlò fún àwa Kristẹni?
Kìkì àwọn tó ń pa gbogbo Òfin tí Ọlọ́run fún wọn nípasẹ̀ Mósè mọ ni òfin Sábáàtì wà fún. (Diutarónómì 5:2, 3; Ìsíkíẹ́lì 20:10-12) Ọlọ́run kò sọ fún àwọn míì pé kí wọ́n máa pa sábáàtì mọ́. Bákan náà, ikú ìrúbọ Jésù kristi ti dá àwọn Júù pàápàá “sílẹ̀ kúrò nínú Òfin,” èyí tó tún ní nínú Òfin Mẹ́wàá. (Róòmù 7:6, 7; 10:4; Gálátíà 3:24, 25; Éfésù 2:15) Kàkà kí àwọn Kristẹni pa Òfin Mósè mọ́, ofin tó ga jù lọ ni wọ́n ń pa mọ́, ìyẹn òfin ìfẹ́.—Róòmù 13:9, 10; Hébérù 8:13.
Èrò tí kò tọ́ tí àwọn èèyàn ní nípa Sábáàtì
Èrò tí kò tọ́: Ọlọ́run dá Sábáàtì sílẹ̀ nígbà tó sinmi lọ́jọ́ keje.
Òótọ́: Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run bù sí ọjọ́ keje, ó sì yà á sí mímọ́; nítorí pé, nínú rẹ̀ ni Ó sinmi kúrò nínú iṣẹ́ Rẹ̀ gbogbo tí Ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:3, Bíbélì Mímọ́) Àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣe ní ọjọ́ keje ìṣẹ̀dá ló wà nínú ẹsẹ yìí, kì í ṣe òfin tó fún àwọn èèyàn. Kó tó di ìgbà ayé Mósè Bíbélì kò mẹ́nu kàn án pé ẹnikẹ́ni pa sábáàtì mọ́.
Èrò tí kò tọ́: Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń pa òfin Sábáàtì mọ́ kí wọ́n tó gba Òfin Mósè.
Òótọ́: Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Jèhófà Ọlọ́run wa bá wa dá májẹ̀mú kan ní Hórébù,” tó wà ní agbègbè òkè Sínáì. Òfin Mósè sì wà lára májẹ̀mú náà. (Diutarónómì 5:2, 12) Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lórí ọ̀rọ̀ Sábáàtì fi hàn pé wọ́n ṣẹ̀ gba òfin náà ni. Tó bá jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń pa òfin Sábáàtì mọ́ tẹ́lẹ̀ nígbà tí wọn wà ní Íjíbítì, báwo wá ni Sábáàtì ṣe máa jẹ́ kí wọ́n rántí ìgbà tí wọn jáde kúrò ní Íjíbítì gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe sọ? (Diutarónómì 5:15) Kì nìdí tí Mósè á fi máa sọ fún wọn pé wọn kò gbọ́dọ̀ kó Mánà lọ́jọ́ keje? (Ẹ́kísódù 16:25-30) Kí sì nìdí tí wọn kò fi mọ ohun tí wọ́n máa ṣe fún ẹni tó kọ́kọ́ rú òfin Sábáàtì?—Númérì 15:32-36.
Èrò tí kò tọ́: Májẹ̀mú tó máa wà títí lọ gbére ni Sábáàtì torí náà ó ṣì wúlò títí dòní.
Òótọ́: Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan sọ pé Sábáàtì jẹ́ “májẹ̀mú títí láé.” (Ẹ́kísódù 31:16, Bíbélì Mímọ́) Àmọ́ ní èdè Hébérù ọ̀rọ̀ náà “títí láé” tún lè túmọ̀ sí “títí lọ,” kò pọn dandan kó jẹ́ títí láé. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì lo òrọ̀ yìí kan náà nígbà tó ń sàpèjúwe bí àkókò tí awọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò fi máa sìn bí àlùfáà ṣe máa gùn tó, àmọ́ ó dópin ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn.—Ẹ́kísódù 40:15; Hébérù 7:11, 12.
Èrò tí kò tọ́: Àwa Kristẹni náà gbọ́dọ̀ pa Sábáàtì mọ́ torí pé Jésù pa á mọ́.
Òótọ́: Jésù pa Sábáàtì mọ́ torí pé Júù ni, láti kékeré ló sì ti ń pa Òfin Mósè mọ́. (Gálátíà 4:4) Lẹ́yìn tí Jésù kú, Ọlọ́run mú Òfin májẹ̀mú kúrò, títí kan òfin Sábáàtì.—Kólósè 2:13, 14.
Èrò tí kò tọ́: Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pa Sábáàtì mọ́ nígbà tó di Kristẹni.
Òótọ́: Pọ́ọ̀lù wọ sínágọ́gù lọ́jọ́ Sábáàtì, ṣùgbọ́n kì í ṣe kó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn Júù náà láti pa Sábáàtì mọ́. (Ìṣe 13:14; 17:1-3; 18:4) Kàkà kó tẹ̀ lé àṣà tó wọ́pọ̀ nígbà yẹn, ó wàásù ìhìn rere nínú àwọn sínágọ́gù bí àwọn tí wọ́n máa ń pè láti wá bá àwọn tó pé jọ fún ìjọsìn sọ̀rọ̀. (Ìṣe 13:15, 32) “Ojoojúmọ́” ni Pọ́ọ̀lù wàásù kì í ṣe ọjọ́ Sábáàtì nìkan.—Ìṣe 17:17.
Èrò tí kò tọ́: Ọjọ́ Sunday ní Sábáàtì àwọn Kristẹni.
Òótọ́: Kò síbì tí Bíbélì ti pàṣẹ pé kí àwọn Kristẹni ya ọjọ́ Sunday tó jẹ́ ọjọ́ àkọ́kọ́ nínú ọ̀sẹ̀ sọ́tọ̀ fún ìsinmi àti ìjọsìn. Bí àwọn ọjọ́ tó kù, ọjọ́ iṣẹ́ ni ọjọ́ Sunday jẹ́ fún àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀. Ìwé The International Standard Bible Encyclopedia sọ pé: “Ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í mú àwọn àṣà ọjọ́ Sábáàtì wọ ọjọ́ Sunday, ìgbà yẹn ni Constantine tó jẹ́ Olú Ọba Róòmù pàṣẹ pé kí àwọn èèyàn má ṣe àwọn iṣẹ́ kan mọ́ lọ́jọ́ Sunday.” a
Kí wá nìdí tí àwọn ẹsẹ̀ Bíbélì kan fi jẹ́ kó dà bí ẹni pé ọjọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ lọjọ́ Sunday? Bíbélì sọ pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù bá àwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀ jẹun pọ̀ “ní ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀,” ìyẹn ọjọ́ Sunday, àmọ́ kì í ṣe ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ló ṣe torí ọjọ́ kejì ló kúrò níbẹ̀. (Ìṣe 20:7) Bákan náà, wọ́n sọ fún àwọn ìjọ kan pé kí wọ́n ya owó kan sọ́tọ̀ ní “gbogbo ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀,” ìyẹn Sunday, láti fi ṣèrànwọ́, àmọ́ àbá to wúlò nípa ètò ìnáwó lèyí jẹ́. Ilé ara wọn ní wọ́n tọ́jú ọrẹ náà sí, kì í ṣe ibi tí wọ́n ti ń ṣèpàdé.—1 Kọ́ríńtì 16:1, 2.
Èrò tí kò tọ́: Kò tọ̀nà láti ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ fún ìsinmi àti ìjọsìn.
Òótọ́: Bíbélì fi olúkálukú sílẹ̀ láti pinnu ohun tó máa ṣe.—Róòmù 14:5.
a Tún wo ìwé New Catholic Encyclopedia, Ẹ̀dà Kejì, Ìdìpọ̀ 13, ojú ìwé 608.