Ṣé Màríà Ni Ìyá Ọlọ́run?
Ohun Tí Bíbélì Sọ
Rárá, Bíbélì kò sọ pé Màríà ni ìyá Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni kò sọ pé kí àwa Kristẹni máa jọ́sìn Màríà tàbí ká máa júbà rẹ̀. a Ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé:
Màríà ò sọ pé òun ni ìyá Ọlọ́run. Ohun tí Bíbélì sọ ni pé Màríà bí “Ọmọ Ọlọ́run,” kì í ṣe Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló bí.—Máàkù 1:1; Lúùkù 1:32.
Jésù Kristi kò sọ pé Màríà ni ìyá Ọlọ́run tàbí pé ó yẹ ká máa júbà rẹ̀. Kódà, nígbà tí obìnrin kan pàfíyèsí àrà ọ̀tọ̀ sí Màríà torí pé òun ló bí Jésù, ńṣe ni Jésù sọ pé: “Ó tì o, kàkà bẹ́ẹ̀, aláyọ̀ ni àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!”—Lúùkù 11:27, 28.
Àwọn ọ̀rọ̀ náà “Ìyá Ọlọ́run” àti “Theotokos” (Ẹni tó bí Ọlọ́run) kò sí nínú Bíbélì.
Kì í ṣe Màríà ni Bíbélì pè ní “Ọbabìnrin Ọ̀run,” òrìṣà kan táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ti di apẹ̀yìndà ń jọ́sìn ni wọ́n ń pè bẹ́ẹ̀. (Jeremáyà 44:15-19) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Ishtar (Astarte) tó jẹ́ abo òrìṣà ilẹ̀ Bábílónì ni wọ́n ń pè ní “Ọbabìnrin Ọ̀run.”
Àwọn Kristẹni ayé àtijọ́ kò jọ́sìn Màríà, wọn ò sì bọlá fún un lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Òpìtàn kan sọ pé àwọn Kristẹni ayé àtijọ́ “kì í sí nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n máa bẹ̀rù pé táwọn bá bọlá fún Màríà lọ́nà àrà ọ̀tọ̀, ìyẹn lè mú káwọn èèyàn máa rò pé ńṣe làwọn ń bọ̀rìṣà.”—In Quest of the Jewish Mary.
Bíbélì sọ pé Ọlọ́run kò ní ìbẹ̀rẹ̀. (Sáàmù 90:1, 2; Aísáyà 40:28) Nígbà tó sì jẹ́ pé kò ní ìbẹ̀rẹ̀, a jẹ́ pé kò lè ní ìyá. Bákan náà, kò lè ṣeé ṣe fún Màríà láti lóyún Ọlọ́run sínú ikùn rẹ̀, torí Bíbélì sọ pé àwọn ọ̀run pàápàá kò lè gba Ọlọ́run.—1 Ọba 8:27.
Ìyá Jésù ni Màríà jẹ́, kì í ṣe “Ìyá Olọ́run”
Júù ni Màríà, àtọmọdọ́mọ Ọba Dáfídì sì ni. (Lúùkù 3:23-31) Ọlọ́run ṣe ojú rere sí i lọ́nà gíga, torí pé ó nígbàgbọ́, ó sì ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn. (Lúùkù 1:28) Ọlọ́run ló yàn án pé kó jẹ́ ìyá Jésù. (Luke 1:31, 35) Màríà àti Jósẹ́fù ọkọ rẹ̀ tún bí àwọn ọmọ mìíràn.—Máàkù 6:3.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Màríà di ọmọ ẹ̀yìn Jésù, kò tún sọ nǹkan púpọ̀ mọ́ nípa rẹ̀.—Ìṣe 1:14.
a Àwọn ẹlẹ́sìn kan ń kọ́ni pé Màríà ni ìyá Ọlọ́run. Wọ́n tiẹ̀ máa ń pè é ní “Ọbabìnrin Ọ̀run” tàbí Theotokos, ìyẹn ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “Ẹni tó bí Ọlọ́run.”