Ǹjẹ́ Ọlọ́run Wà?
Ohun tí Bíbélì sọ
Bẹ́ẹ̀ ni, Bíbélì fún wa láwọn ẹ̀rí tó ṣe kedere pé Ọlọ́run wà. Ó gbà wá níyànjú pé ká lo “agbára ìmọnúúrò” wa àti “agbára ìmòye” wa ká lè mọ̀ pé Ọlọ́run wà, kì í ṣe ká kàn gbà nítorí pé àwọn ẹlẹ́sìn sọ bẹ́ẹ̀. (Róòmù 12:1; 1 Jòhánù 5:20) Ronú lórí àwọn ẹ̀rí tí Bíbélì fún wa yìí:
Bí gbogbo nǹkan tó wà ní àgbáálá ayé wa ṣe wà létòletò fi hàn pé Ẹlẹ́dàá kan ló ṣètò rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Dájúdájú, olúkúlùkù ilé ni a kọ́ láti ọwọ́ ẹnì kan, ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run.” (Hébérù 3:4) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Bíbélì yìí kò pọ̀, síbẹ̀ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n gbà pé ọ̀rọ̀ ńlá ni. a
Ó máa ń wu àwa èèyàn láti mọ ìdí tá a fi wà láyé. Kódà, ká a ní gbogbo ohun tá a fẹ́ láyé yìí, nínú lọ́hùn-ún, a ṣì máa ń fẹ́ mọ ohun tá a wá ṣe láyé. Ìfẹ́ yìí ni Bíbélì pé ní ‘àìní ti ẹ̀mí,’ ó sì ní nínú ìfẹ́ láti mọ Ọlọ́run, ká sì jọ́sìn rẹ̀. (Mátíù 5:3; Ìṣípayá 4:11) Kì í ṣe pé àìní tẹ̀mí yìí jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run wà nìkan, ó tún ń jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì fẹ́ ká rí ìdáhùn sí ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn.—Mátíù 4:4.
Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ tipẹ́tipẹ́ nímùúṣẹ gẹ́lẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ. Bíbélì sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe máa ṣẹ, bí wọ́n ṣe nímùúṣẹ gẹ́lẹ́ fi hàn pé àtọ̀dọ̀ ọlọgbọ́n kan tó ju èèyàn lọ làwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà ti wá.—2 Pétérù 1:21.
Àwọn tó kọ Bíbélì ní òye nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ju àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ayé ọjọ́un lọ. Bí àpẹẹrẹ, láyé ìgbàanì, ọ̀pọ̀ rò pé ẹranko ńlá kan bí erin, ìmàdò tàbí màlúù ló gbé ayé dúró. Àmọ́ ohun tí Bíbélì sọ yàtọ̀ síyẹn, ó sọ pé Ọlọ́run “so ilẹ̀ ayé rọ̀ sórí òfo.” (Jóòbù 26:7) Bákan náà, Bíbélì sọ ní tààràtà pé ayé jẹ́ “òbìrìkìtì” tàbí pé ó rí rogodo. (Aísáyà 40:22) Ọ̀pọ̀ lónìí gbà pé ohun tó mú káwọn tó kọ Bíbélì ní irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ ní pé àtọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni wọ́n ti gbà á.
Bíbélì dáhùn ọ̀pọ̀ àwọn ìbéèrè tó ta kókó, àwọn ìbéèrè tó jẹ́ pé béèyàn ò bá rí ìdáhùn tó jóòótọ́ sí wọn, ó lè mú kéèyàn rò pé kò sí Ọlọ́run. Àpẹẹrẹ irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ ni: Tí Ọlọ́run bá jẹ alágbára tó sì nífẹ̀ẹ́ wa, kí ló dé tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń jìyà tí ìwà ibi sì pọ̀? Kí ló dé tó fi jẹ́ pé kàkà kí ìsìn mú ká wà ní ìrẹ́pọ̀, wàhálà ló máa ń dá sílẹ̀?—Títù 1:16.
a Bí àpẹẹrẹ, Allan Sandage tó jẹ́ onímọ̀ nípa sánmà sọ nípa àgbáálá ayé wa pé: “Ó ṣòro fún mi láti gbà pé àwọn nǹkan tó wà létòlétò báyìí kàn lè ṣàdédé wà. Nǹkan kan ló ní láti máa ṣamọ̀nà wọn. Èmi ò mọ̀ bóyá Ọlọ́run wà, àmọ́ kò sí àlàyé míì tó mọ́gbọ́n dání nípa bí àwọn nǹkan yìí ṣe wà ju pé ẹnì kan ló dá wọn.”