Kí Ni Òfin Oníwúrà?
Ohun tí Bíbélì sọ
Ọ̀rọ̀ náà “Òfin Oníwúrà” kò sí níbì kankan nínú Bíbélì. Ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń pè bẹ́ẹ̀ ni ìlànà ìwà híhù kan tí Jésù sọ. Nínú Ìwàásù Orí Òkè, Jésù sọ pé: “Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn èèyàn ṣe sí yín ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe sí wọn.” (Mátíù 7:12; Lúùkù 6:31) Wọ́n tún máa ń sọ Òfin Oníwúrà yẹn báyìí: “Ohun tó o bá fẹ́ káwọn èèyàn ṣe sí ẹ ni kó o ṣe fún wọn.”—Encyclopedia of Philosophy.
Kí ni Òfin Oníwúrà náà túmọ̀ sí?
Òfin Oníwúrà náà gbà wá níyànjú pé tá a bá ṣe fẹ́ káwọn èèyàn ṣe sí wa ni ká ṣe sí wọn. Bí àpẹẹrẹ, inú wa máa ń dùn táwọn èèyàn bá bọ̀wọ̀ fún wa, tí wọ́n bá ṣenúure sí wa tàbí tí wọ́n bá fìfẹ́ hàn sí wa. Ohun tó yẹ káwa náà “máa ṣe sí wọn” gẹ́lẹ́ nìyẹn.—Lúùkù 6:31.
Ṣé Òfin Oníwúrà yìí wúlò?
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé kò síbi tí Òfin Oníwúrà yìí ò ti wúlò. Bí àpẹẹrẹ, ó lè . . .
Mú kí ọkọ àti ìyàwó túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn.—Éfésù 5:28, 33.
Ran àwọn òbí lọ́wọ́ kí wọ́n lè tọ́ àwọn ọmọ yanjú.—Éfésù 6:4.
Jẹ́ kí àjọṣe tó wà láàárín àwọn ọ̀rẹ́, aládùúgbò àtàwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ lágbára.—Òwe 3:27, 28; Kólósè 3:13.
Ìlànà kan náà ni Májẹ̀mú Láéláé àti Òfin Oníwúrà dá lé. Ìlànà ìwà híhù tí Jésù kọ́ wa yìí ni “ohun tí Òfin [ìyẹn ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì] àti àwọn Wòlíì túmọ̀ sí.” (Mátíù 7:12) Lédè míì, lára ohun tí gbogbo Májẹ̀mú Láéláé dá lé ni Òfin Oníwúrà gbé yọ, ohun náà ni ìfẹ́ fún aládùúgbò.—Róòmù 13:8-10.
Ṣé ohun táwọn èèyàn lè ṣe fún wa nìkan ni Òfin Oníwúrà dá lé?
Rárá o. Àmọ́, ọ̀rọ̀ nípa fífúnni ni òfin náà tẹnu mọ́. Nígbà tí Jésù fún wa ní Òfin Oníwúrà, ó fẹ́ ká máa fi òfin yìí sílò bá a ṣe ń hùwà sí gbogbo èèyàn títí kan àwọn ọ̀tá wa pàápàá. (Lúùkù 6:27-31, 35) Torí náà, Òfin Oníwúrà ń gbà wá níyànjú pé ká máa ṣe rere sí gbogbo èèyàn.
Báwo lo ṣe lè fi Òfin Oníwúrà náà sílò?
1. Ní àkíyèsí. Máa wo àwọn tó yí ẹ ká dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, o lè rí i tẹ́nì kan ń tiraka láti gbé ẹrù kan tó wúwo, o lè gbọ́ pé aládùúgbò ẹ wà nílé ìwòsàn, tàbí kó o ríi pé inú ẹni tẹ́ e jọ ń ṣiṣẹ́ kò dùn. Tó o bá ń “wá ire àwọn ẹlòmíì,” ó dájú pé wàá túbọ̀ máa sọ̀rọ̀ tàbí ṣe ohun tá á múnú àwọn èèyàn dùn.—Fílípì 2:4.
2. Máa fi ara ẹ sípò àwọn míì. Bi ara rẹ pé, ká ní èmi ni irú nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sẹ́ni yìí ṣẹlẹ̀ sí, báwo ló ṣe máa rí lára mi? (Róòmù 12:15) Tó o bá ń gbìyànjú láti mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára àwọn míì, ìyẹn á jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lé ràn wọ́n lọ́wọ́.
3. Fi sọ́kàn pé gbogbo wa yàtọ̀ síra. Fi sọ́kàn pé gbogbo wa ò rí bákan náà. Ohun táwọn kan fẹ́ káwọn míì ṣe fún wọn lè yàtọ̀ sóhun tíwọ ń fẹ́. Torí náà, ohun táwọn èèyàn bá nífẹ̀ẹ́ sí ni kó o máa ṣe fún wọn.—1 Kọ́ríńtì 10:24.