Ǹjẹ́ A Lè Mọ Ẹni Tó Kọ Bíbélì?
Ohun tí Bíbélì sọ
Wọ́n ti sọ fún ọ̀pọ̀ èèyàn pé a ò lè mọ ẹni tó kọ Bíbélì. Àmọ́, Bíbélì sábà máa ń sọ àwọn tó kọ̀ ọ́. Àwọn apá kan bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ bí “ọ̀rọ̀ Nehemáyà,” “Ìran Aísáyà,” àti ‘ọ̀rọ̀ Jèhófà tí ó tọ Jóẹ́lì wá.’—Nehemáyà 1:1; Aísáyà 1:1; Jóẹ́lì 1:1.
Ọ̀pọ̀ àwọn tó kọ Bíbélì gbà pé àwọn kọ̀wé lórúkọ Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà àti pé òun ló darí àwọn. Ó lé ní ọ̀ọ́dúnrún [300] ìgbà táwọn wòlíì tó kọ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sọ pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí.” (Ámósì 1:3; Míkà 2:3; Náhúmù 1:12) Àwọn ańgẹ́lì ló sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún àwọn míì lára àwọn tó kọ Bíbélì.—Sekaráyà 1:7, 9.
Nǹkan bí ogójì [40] ọkùnrin ló kọ Bíbélì, ó sì gbà wọ́n ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀jọ [1,600] ọdún. Àwọn kan lára wọn kọ ju ìwé Bíbélì kan lọ. Bíbélì jẹ́ ibi ìkówèésí kékeré tó ní ìwé mẹ́rìndínláàádọ́rin [66]. Ìwé mọ́kàndínlógójì [39] tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, tí ọ̀pọ̀ ń pè ní Májẹ̀mú Láéláé àti ìwé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27] tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì, tí wọ́n sábà máa ń pè ní Májẹ̀mú Tuntun ló para pọ̀ di Bíbélì.