Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ

Bí Ẹ Ṣe Lè Máa Fìfẹ́ Hàn Síra Yín

Bí Ẹ Ṣe Lè Máa Fìfẹ́ Hàn Síra Yín

 Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, ṣe ni ìfẹ́ tí àwọn tọkọtaya kan máa ń fi hàn síra wọn máa ń túbọ̀ dín kù. Tírú ẹ̀ bá ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbéyàwó yín, báwo ló ṣe yẹ kó rí lára ẹ?

 Ohun tó yẹ kó o mọ̀

 Ó ṣe pàtàkì kẹ́ ẹ máa fìfẹ́ hàn síra yín kí ìdè ìgbéyàwó yín lè lágbára. Bó ṣe jẹ́ pé ó ṣe pàtàkì kéèyàn máa jẹun, kó sì máa mumi déédéé tó bá máa ní ìlera tó dáa, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe pàtàkì kí tọkọtaya máa fìfẹ́ hàn síra wọn tí ìgbéyàwó wọn bá máa ládùn, tó sì máa pẹ́. Kódà, lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tí tọkọtaya bá ti ṣègbéyàwó, ó yẹ kí ọkọ máa fi dá ìyàwó ẹ̀ lójú látìgbàdégbà pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ dénú àti pé òun ò fọ̀rọ̀ ẹ̀ ṣeré, ó sì yẹ kí ìyàwó náà máa ṣe bẹ́ẹ̀ sí ọkọ ẹ̀.

 Ìfẹ́ tòótọ́ kì í wá ire tara rẹ̀ nìkan. Ẹni tó bá ní ìfẹ́ tòótọ́ máa ń wá bí ẹnì kejì á ṣe máa láyọ̀. Torí náà, dípò kó jẹ́ pé ìgbà tó bá wu tọkọtaya nìkan ni wọ́n á máa fìfẹ́ hàn síra wọn, ọkọ tàbí aya tó bá gba ti ẹnì kejì rẹ̀ rò á máa fòye mọ ìgbà tí ẹnì kejì rẹ̀ nílò kóun fìfẹ́ hàn sí i, á sì gbìyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀.

 Àwọn ìyàwó sábà máa ń nílò kí ọkọ wọn fìfẹ́ hàn sí wọn ju báwọn ọkọ ṣe nílò rẹ̀ lọ. Ọkọ kan lè nífẹ̀ẹ́ ìyàwó ẹ̀ gan-an. Àmọ́ tọ́ bá jẹ́ pé ìgbà tó bá jí láàárọ̀ àbí ìgbà tó fẹ́ lọ sùn lálẹ́ nìkan ló ń fìfẹ́ yẹn hàn sí i, tàbí tó jẹ́ pé tí wọ́n bá fẹ́ ní ìbálòpọ̀ nìkan ló ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè má dá ìyàwó ẹ̀ lójú bóyá lóòótọ́ ló nífẹ̀ẹ́ òun dénú. Ohun tó dáa jù ni kó máa fìfẹ́ hàn síyàwó ẹ̀ jálẹ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.

 Ohun tó o lè ṣe

 Máa sọ̀rọ̀ ìfẹ́. Àwọn ọ̀rọ̀ kéékèèké bíi “Mo nífẹ̀ẹ́ ẹ” tàbí “Ọmọlójú mi lo jẹ́” lè jẹ́ kí ẹnì kejì ẹ mọ̀ pé o mọyì òun.

 Ìlànà: “Lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu ń sọ.”​​Mátíù 12:34.

 Àbá: Kò pọn dandan kó jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan ni wàá fi máa fìfẹ́ hàn. O lè kọ ọ́ sínú ìwé, kó o fi ránṣẹ́ látorí e-mail tàbí kó o tẹ àtẹ̀jíṣẹ́.

 Máa fìfẹ́ hàn nínú ìwà ẹ. Tó o bá dì mọ́ ẹnì kejì ẹ, tó o fẹnu kò ó lẹ́nu tàbí tẹ́ ẹ kàn dira yín lọ́wọ́ mú, ó lè jẹ́ kó hàn pé òótọ́ lo sọ nígbà tó o sọ fún un pé “mo nífẹ̀ẹ́ ẹ.” O tún lè fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ dénú tó o bá rọra fọwọ́ kàn án lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́, tó o ṣíjú ìfẹ́ wò ó tàbí tó ò ń fún un lẹ́bùn látìgbàdégbà. Ìwọ ọkọ sì lè ran ìyàwó ẹ lọ́wọ́, bíi kó o bá a gbé ẹrù, kó o bá a ṣílẹ̀kùn, kó o fọ abọ́ tàbí aṣọ, tàbí kó o dáná. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé tí ọkọ kan bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, ó kọjá pé ó kàn ń ran ìyàwó ẹ̀ lọ́wọ́, ṣe ló ń fìfẹ́ hàn sí i!

 Ìlànà Bíbélì: “Ẹ jẹ́ kí a nífẹ̀ẹ́, kì í ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí pẹ̀lú ahọ́n [nìkan], bí kò ṣe ní ìṣe àti òtítọ́.”​​1 Jòhánù 3:​18.

 Àbá: Máa gba tí ẹnì kejì ẹ rò bó o ṣe máa ń ṣe nígbà tẹ́ ẹ̀ ń fẹ́ra yín sọ́nà.

 Ẹ máa wáyè fún ara yín. Tí ẹ̀yin méjèèjì bá jọ ń dá wà, ó máa jẹ́ kí ìdè ìgbéyàwó yín túbọ̀ lágbára, á sì jẹ́ kó dá ẹnì kejì ẹ lójú pé inú ẹ máa ń dùn láti wà lọ́dọ̀ òun. Ká sòótọ́, tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ ti bímọ tàbí tó jẹ́ pé àwọn nǹkan pàtàkì pọ̀ tó yẹ kẹ́ ẹ máa bójú tó lójoojúmọ́, ó lè má rọrùn pé kí ẹ̀yin méjèèjì ráyè dá wà. Àmọ́ ẹ lè ṣètò láti jọ máa ṣe nǹkan kan tó rọrùn déédéé, bíi kí ẹ̀yin méjèèjì nìkan jọ máa gbatẹ́gùn jáde.

 Ìlànà Bíbélì: “Máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.”​—Fílípì 1:​10.

 Àbá: Àwọn tọkọtaya kan tọ́wọ́ wọn máa ń dí máa ń wáyè láti jọ máa “gbafẹ́ jáde lálẹ́” déédéé tàbí láti jọ máa “gbafẹ́ jáde lópin ọ̀sẹ̀” déédéé, káwọn méjèèjì lè máa ráyè wà pa pọ̀.

 Mọ ẹnì kejì ẹ. Bí kálukú ṣe máa ń nílò kí wọ́n fìfẹ́ hàn sí i tó máa ń yàtọ̀ síra. Kí ẹ̀yin méjèèjì jọ sọ̀rọ̀ nípa bí kálukú yín ṣe fẹ́ kí ẹnì kejì máa fìfẹ́ hàn sí òun, kẹ́ ẹ sì jọ sọ ọ́ bóyá ó máa nílò kẹ́ ẹ fi kún bẹ́ ẹ ṣe ń fìfẹ́ hàn síra yín. Kó o wá sapá láti rí i pé ò ń ṣe ohun tí ẹnì kejì ẹ fẹ́. Má gbàgbé pé ó ṣe pàtàkì kẹ́ ẹ máa fìfẹ́ hàn síra yín kí ìdè ìgbéyàwó yín lè lágbára.

 Ìlànà Bíbélì:Ìfẹ́ . . . kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.”​​1 Kọ́ríńtì 13:​4, 5.

 Àbá: Dípò kó o máa sọ fún ẹnì kejì ẹ pé ìfẹ́ tó ń fi hàn sí ẹ ò tó, bi ara ẹ pé, ‘Kí ni mo lè ṣe tó máa mú kó wu ẹnì kejì mi láti túbọ̀ fìfẹ́ hàn sí mi?’