ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ
Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Ẹnì Kejì Ẹ Bá Hùwà Tó Ń Múnú Bí Ẹ
Ìgbà tí nǹkan bá wù ẹ́ lo máa ń ṣe é; ọkọ tàbí aya rẹ fẹ́ kéèyàn tí múra nǹkan sílẹ̀ kó tó ṣe é.
Èèyàn jẹ́jẹ́ tí kì í fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ ni ẹ́; ọkọ tàbí aya rẹ túra ká ara ẹ̀ sì yá mọ́ọ̀yàn.
Ṣé ọkọ tàbí aya rẹ máa ń hùwà tó ń múnú bí ẹ? Tó o bá ń ronú nípa ẹ̀ ṣáá, ìyẹn lè fa ìṣòro nínú ìgbéyàwó yín. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé “ẹni tó bá ń tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ ṣáá ń tú ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ká.”—Òwe 17:9.
Dípò tí wàá fi jẹ́ kí ìwà tó ń múnú bí ẹ dá ìjà sílẹ̀ láàárín ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ, o lè kọ́ bí wàá ṣe máa fojú tó dáa wo ìwà náà.
Nínú àpilẹ̀kọ yìí
Ojú tó yẹ kó o máa fi wo ìwà tó ń múnú bí ẹ
Ànímọ́ kan tó ń múnú bí ẹ lára ẹnì kejì ẹ lè jẹ́ ànímọ́ kan náà tó o nífẹ̀ẹ́ sí. Ronú lórí àwọn àpẹẹrẹ mẹ́ta yìí:
“Ọkọ mi máa ń pẹ́ kó tó ṣe nǹkan tán, kì í sì í tètè múra tá a bá fẹ́ lọ síbì kan. Ṣùgbọ́n ìwà rẹ̀ yìí náà ló mú kó jẹ́ onísùúrù, ó sì máa ń ní sùúrù fémi náà. Bó ṣe ń pẹ́ yẹn máa ń bí mi nínú nígbà míì, ṣùgbọ́n ó tún wà lára ohun tó fi ń wù mí.”—Chelsea.
“Ìyàwó mi kì í fẹ́ kí ohunkóhun wọ́lẹ̀; torí ẹ̀ ó máa ń fẹ́ ṣètò gbogbo nǹkan, ìyẹn sì máa ń bí mi nínú nígbà míì. Ṣùgbọ́n, bó ṣe máa ń kíyè sí gbogbo nǹkan kínníkínní yẹn kì í jẹ́ kí ohunkóhun bá a lójijì.”—Christopher.
“Ó jọ pé ọkọ mi kì í fi bẹ́ẹ̀ ka nǹkan sí, ìyẹn sì máa ń mú mi rẹ̀wẹ̀sì. Síbẹ̀, bí kò ṣe máyé le yẹn jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ tó mú kí n fẹ́ràn rẹ̀. Kì í káyà sókè tá a bá níṣòro, ìyẹn sì máa ń wú mi lórí gan-an.”—Danielle.
Bí Chelsea, Christopher àti Danielle ṣe sọ, ìwà kan tí ẹnì kejì ẹ ní lè múnú ẹ dùn lápá kan, kí ìwà kan náà sì múnú bí ẹ lójọ́ míì. Bí ọ̀rọ̀ bá sì ti rí bẹ́ẹ̀, kò sí bó o ṣe lè kórìíra apá tó ń múnú bí ẹ láì gbójú fo apá tó dáa.
Ṣùgbọ́n, àwọn ìwà kan wà tí ò dáa rárá. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé àwọn kan máa “ń tètè bínú.” (Òwe 29:22) Bọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ kéèyàn sapá láti mú “gbogbo inú burukú, ìbínú, ìrunú, ariwo àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò.” a—Éfésù 4:31.
Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ pé ṣe ni ìwà kan wulẹ̀ ń múnú bí ẹ, tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Ẹ máa fara dà á fún ara yín . . . kódà tí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí láti fẹ̀sùn kan ẹlòmíì.”—Kólósè 3:13.
Lẹ́yìn yẹn, gbìyànjú láti wo ibi tẹ́nì kejì ẹ dáa sí i, àwọn ohun tó ṣeé ṣe kó fà ẹ́ mọ́ra lára ẹ̀. Ọkọ kan tó ń jẹ́ Joseph sọ pé, “Ṣe ni ẹni tó bá ń ronú ṣáá nípa ìwà tó ń múnú bí i lára ẹnì kejì ẹ̀ dà bí ẹni tó ń wo bí ara dáyámọ́ńdì kan ṣe rí gbágungbàgun ṣùgbọ́n tí kò mọyì bó ṣe ń kọ mànà.”
Ohun tẹ́ ẹ lè jọ jíròrò
Kí kálukú kọ́kọ́ ronú lórí àwọn ìbéèrè yìí. Lẹ́yìn náà, kẹ́ ẹ jọ jíròrò ìdáhùn yín.
Ṣé ìwà kan wà tí ọkọ tàbí aya rẹ ń hù tó o ronú pé ó máa ń fa ìjà láàárín yín? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwà wo ni?
Ṣé ìwà burúkú ni, àbí ó kàn wulẹ̀ ń múnú bí ẹ?
Ṣé ìwà náà ní ibi tó dáa sí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ibo ló dáa sí, kí sì nìdí tí ìyẹn fi wù ẹ́ lára ìwà ọkọ tàbí aya rẹ?
a Wo àwọn àpilẹ̀kọ náà ““Bó o Ṣe Lè Kápá Ìbínú Rẹ,” “Bí Ẹ Ṣe Lè Yẹra Fún Sísọ Ọ̀rọ̀ Líle Síra Yín,” àti “Bí Ẹ Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Bíbá Ara Yín Jiyàn.”