Kí Nìdí Tí Ẹ Fi Ń Lọ Láti Ilé Dé Ilé?
Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n “sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mátíù 28:19, 20) Nígbà tí Jésù rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àkọ́kọ́ jáde, ó ní kí wọ́n lọ bá àwọn èèyàn nínú ilé wọn. (Mátíù 10:7, 11-13) Lẹ́yìn tí Jésù kú, àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ń bá a nìṣó láti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún àwọn èèyàn “ní gbangba àti láti ilé dé ilé.” (Ìṣe 5:42; 20:20) Àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ yẹn là ń tẹ̀ lé, èyí ti jẹ́ ká mọ̀ pé ìwàásù ilé-dé-ilé jẹ́ ọ̀nà tó dára láti gbà bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀.