À Ń Ran Àwọn Adití Lọ́wọ́ ní “Orílẹ̀-èdè Tó Rẹwà Jù ní Agbedeméjì Ayé”
Ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù àwọn adití ló ń gbé ní orílẹ̀-èdè Indonéṣíà. Àwọn èèyàn mọ orílẹ̀-èdè yìí sí Orílẹ̀-èdè Tó Rẹwà Jù ní Agbedeméjì Ayé. Káwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè ran àwọn adití yìí lọ́wọ́, a ṣètò ọ̀pọ̀ ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì, a sì ṣètò ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní Èdè Adití ti Indonéṣíà. Àwọn kan ti kíyè sí ìsapá wa yìí.
Àpéjọ Àgbègbè ní Édè Adití
Lódún 2016, nílùú Medan, ní North Sumatra, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe àpéjọ àgbègbè kan ní Èdè Adití ti Indonéṣíà. Òṣìṣẹ́ kan tó jẹ́ ẹ̀ṣọ́ pàtàkì lágbègbè yẹn lọ síbi àpéjọ náà, ó sì yin àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí bá a ṣe dá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ lọ́fẹ̀ẹ́. Ohun tó rí wú u lórí débi pé ó tiẹ̀ gbìyànjú láti máa fọwọ́ ṣàpèjúwe bíi tàwọn yòókù nígbà tí wọ́n ń kọrin.
Alábòójútó ibi tá a ti ṣe àpéjọ náà sọ pé àpéjọ náà “lọ láìsí ìdíwọ́ kankan. Á wù mí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá ń ṣètò irú àwọn ìkórajọ tó ń ṣàǹfààní bí eléyìí láti máa fi ran àwọn adití tó wà láwùjọ wa lọ́wọ́.” Ó fi kún un pé nígbà tí ẹni tó ni ibi tí wọ́n ti ṣe àpéjọ náà gbọ́ pé àwọn adití ni àpéjọ náà wà fún, “ó wù ú láti ṣe nǹkan kan tó dáa fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ló bá sọ fún mi pé kí n ṣètò oúnjẹ ọ̀sán fún [gbogbo àwọn 300] tó wá síbi àpéjọ náà.”
Wọ́n Mọrírì Àwọn Fídíò Èdè Adití
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún máa ń wá àwọn adití lọ sílé níkọ̀ọ̀kan ká lè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. A sábà máa ń lo àwọn fídíò Èdè Adití ti Indonéṣíà tá a dìídì ṣe láti ran àwọn adití lọ́wọ́ kí ayé wọn lè nítumọ̀, kó sì ládùn.
Mahendra Teguh Priswanto, tó jẹ́ igbá-kejì olórí Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Àwọn Adití nílùú Semarang, ní Central Java, lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà, sọ pé: “Ó yẹ ká yìn yín torí iṣẹ́ tẹ́ ẹ̀ ń ṣe láti bójú tó àwọn adití àtàwọn ohun tí wọ́n nílò. Bí àpẹẹrẹ, fídíò Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀ wúlò gan-an. A máa mọrírì ẹ̀ tẹ́ ò bá dáwọ́ iṣẹ́ yìí dúró.”
Wọ́n “Nífẹ̀ẹ́ Wa”
Iṣẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ti ran obìnrin kan tó ń jẹ́ Yanti lọ́wọ́ gan-an. Adití ni, ó ṣàlàyé pé: “Yẹ̀yẹ́ làwọn èèyàn sábà máa ń fi àwa adití ṣe, àmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa. Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọn kì í ṣe adití ló ti kọ́ èdè àwọn adití kí wọ́n lè máa fi kọ́ àwọn adití nípa Ẹlẹ́dàá wa, kí wọ́n sì lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tún ayé wọn ṣe. Ìsapá tí wọ́n ń ṣe látọkàn wá yìí wú mi lórí gan-an.”
Nígbà tó yá, Yanti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì ti wà lára àwọn atúmọ̀ èdè tó ń ṣe àwọn fídíò jáde ní Èdè Adití ti Indonéṣíà. Ó sọ pé: “Àwọn fídíò tá à ń ṣe máa ń ṣèrànwọ́ fáwọn tí ò fi bẹ́ẹ̀ mọ èdè náà kí wọ́n lè túbọ̀ mọ̀ ọ́n. Àwọn fídíò yẹn sì tún máa ń kọ́ àwọn èèyàn lóhun tí wọ́n lè ṣe kí ayé wọn lè nítumọ̀, kó ládùn, kó sì lóyin.”