ÌKÀNNÌ JW.ORG
Fi Ìlujá Àpilẹ̀kọ, Fídíò Tàbí Ìtẹ̀jáde Kan Ránṣẹ́
O lè fi ìlujá àpilẹ̀kọ, fídíò tàbí ìtẹ̀jáde èyíkéyìí tó wà lórí ìkànnì jw.org ránṣẹ́ sí ẹnì kan.
Tẹ bọ́tìnnì tá a pè ní Fi Ránṣẹ́ tó máa ń wà nísàlẹ̀ àpilẹ̀kọ tàbí fídíò èyíkéyìí, kó o lè fi ìlujá abala yẹn ránṣẹ́.
Tẹ bọ́tìnnì tá a pè ní Fi Ránṣẹ́ tó máa ń wà nísàlẹ̀ ìtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn bọ́tìnnì tó o fi máa wa ìtẹ̀jáde náà, kó o lè fi ìlujá ìtẹ̀jáde náà ránṣẹ́.
Tó o bá ti tẹ bọ́tìnnì náà, ohun méjì lo máa rí:
Wàá rí àpótí gbọọrọ kan tó ní oríṣiríṣi lẹ́tà, àwọn lẹ́tà yìí ni ìlujá abala tó o fẹ́ fi ránṣẹ́. Ṣe ẹ̀dà ìlujá náà sínú e-mail tàbí kó o ṣe ẹ̀dà ẹ̀ sórí fóònù rẹ, kó o wá fi ránṣẹ́.
Wàá rí ìlujá tá a pè ní Fi Ránṣẹ́ lórí e-mail. Tó o bá tẹ ìlujá yìí, ó máa ṣí e-mail kan fún ẹ kó o lè fi ránṣẹ́, àkòrí àpilẹ̀kọ tàbí ìtẹ̀jáde náà máa wà lókè, ìlujá àpilẹ̀kọ tàbí ìtẹ̀jáde náà á sì wà nísàlẹ̀. (Àkíyèsí: Kọ̀ǹpútà lè ní kó o yan irú email tó o fẹ́ lò.)